ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 11/10 ojú ìwé 8
  • Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
  • Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
  • Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
  • Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
km 11/10 ojú ìwé 8

Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn

Ilé Ìṣọ́ November 1

“Ǹjẹ́ o rò pé àwọn nǹkan tí à ń ṣe kan àwọn ańgẹ́lì? [Jẹ́ kó fèsì.] Bíbélì sọ ohun kan tó gbàfiyèsí. [Ka Lúùkù 15:10.] Nínú àpilẹ̀kọ yìí, wàá rí bí Jésù ṣe sọ ipa táwọn ẹ̀dá ẹ̀mí ń ní lórí wa.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 16 hàn án.

Ji! October–December

“Àwọn kan máa ń sọ pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò gba Jésù gbọ́. Kí lèrò tìẹ? [Jẹ́ kó fèsì.] Òótọ́ ibẹ̀ ni pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gba Jésù gbọ́, a sì fara mọ́ ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ nípa rẹ̀. [Ka Kólósè 1:15.] O lè mọ irú èèyàn tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ dáadáa tó o bá ṣàyẹ̀wò ohun tá a gbà gbọ́, gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú ìwé ìròyìn yìí.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 8 hàn án.

Ilé Ìṣọ́ December 1

“Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà gbọ́ pé àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí onílàákàyè kan wà ní ilẹ̀ ẹ̀mí, wọ́n sì máa ń nípa lórí ohun tá a bá ń ṣe. Kí lèrò tìẹ? [Jẹ́ kó fèsì. Kó o wá ka Ìṣípayá 12:7-9.] Ìwé ìròyìn yìí jẹ́ ká mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí àti ipa tí wọ́n máa ń ní lórí wa, ó sì tún jẹ́ ká mọ̀ bóyá a lè bá wọn sọ̀rọ̀.”

Ji! October–December

“Kí lèrò rẹ nípa àwọn fídíò tó máa ń ṣàfihàn àwọn ẹ̀mí èṣù àtàwọn àjẹ́? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé Mímọ́ sọ pé ọ̀tá Ọlọ́run ni àwọn ẹ̀mí èṣù àti pé Ọlọ́run ti ‘fi wọ́n pa mọ́ de ìdájọ́.’ [Ka 2 Pétérù 2:4.] Àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ ni ojú ìwé 22 nínú ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé ìdí tí kò fi bọ́gbọ́n mu pé ká tipasẹ̀ eré ìnàjú fi ara wa sábẹ́ ìdarí àwọn ẹ̀mí èṣù.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́