Àwọn Kókó Inú Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn
Ní oṣù June, iye akéde tó ròyìn jẹ́ ọ̀kẹ́ márùndínlógún àti ọ̀tà lé rúgba lé mẹ́rin [300,264]. Láti ìbẹ̀rẹ̀ ọdún iṣẹ́ ìsìn 2010, kò tíì sí oṣù kankan tí iye àwọn akéde tó ròyìn pọ̀ tó báyìí. Iye yìí tún fi ẹgbẹ̀rún mẹ́sàn-án, ọgọ́rùn-ún mẹ́fà àti méjìlá [9,612] pọ̀ ju iye àwọn tó ròyìn ní oṣù June ọdún 2009. Ẹ jẹ́ ká wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù yìí ní kánjúkánjú, níwọ̀n bá a ti mọ̀ pé àkókò tó ṣẹ́ kù ti dín kù.—1 Kọ́r. 7:29; 2 Tím. 4:2.