Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a máa lò ní November: Kí Ló Wà Nínú Bíbélì? Kí ẹ lo àwọn ìwé pẹlẹbẹ yìí ní àfikún sí ìwé pẹlẹbẹ tuntun náà: Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi?, Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run! àti Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I? December: Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí. Bí àwọn ọmọdé bá wà nínú ilé náà, kẹ́ ẹ lo ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà. January: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Ẹ fún ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa ní ìwé àṣàrò kúkúrú náà Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́?, kẹ́ ẹ sì sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. February: Ẹ lè lo Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé tàbí Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà.