Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ilé Ìṣọ́ April 1
“Àwọn kan gbà gbọ́ pé kádàrá ló ń darí ìgbésí ayé èèyàn, àwọn míì sì sọ pé fúnra èèyàn ló máa yan ohun tó bá fẹ́. Kí lèrò tìẹ? [Jẹ́ kó fèsì.] Gbọ́ ọ̀rọ̀ pàtàkì yìí. [Ka Oníwàásù 9:11.] Àpilẹ̀kọ yìí jẹ́ ká mọ ìdáhùn Bíbélì sí ìbéèrè yìí, ‘Ṣé Ọlọ́run ti kádàrá wa?’” Lo àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 26.
Jí! April–June
“Gbogbo wa la máa ń fẹ́ láwọn ọ̀rẹ́ àtàtà. Irú àwọn ànímọ́ wo lò ń fẹ́ kí ọ̀rẹ́ ẹ ní? [Jẹ́ kó fèsì.] Gbọ́ àpèjúwe yìí nínú Bíbélì. [Ka Òwe 17:17.] Àpilẹ̀kọ yìí sọ àwọn àbá lórí béèyàn ṣe lè yan ọ̀rẹ́ àtàtà àti béèyàn ṣe lè jẹ́ ọ̀rẹ́ àtàtà fáwọn ẹlòmíì.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 18 hàn án.
Ilé Ìṣọ́ May 1
“Kí lo rò pé ó lè mú kó ṣòro fún ẹnì kan láti gba Ọlọ́run gbọ́? [Jẹ́ kó fèsì.] Ẹsẹ Bíbélì yìí jẹ́ ká mọ̀ pé ìgbàgbọ́ ṣe pàtàkì. [Ka Hébérù 11:6.] Ìwé ìròyìn yìí sọ ohun mẹ́rin téèyàn lè ṣe láti jẹ́ kí ìgbàgbọ́ ẹ̀ jinlẹ̀.”
Jí! April–June
“Ọ̀pọ̀ ìgbéyàwó ló máa ń tú ká nítorí àìṣòótọ́. Ǹjẹ́ o rò pé fífi ìmọ̀ràn Bíbélì yìí sílò lè jẹ́ kí ìgbéyàwó tọ́jọ́? [Ka Mátíù 5:28. Lẹ́yìn náà kó o jẹ́ kó fèsì.] Àpilẹ̀kọ yìí lo Bíbélì láti ran tọkọtaya lọ́wọ́ kí wọ́n má bàa dẹni tó ń dalẹ̀ ara wọn.” Ló àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 28.