Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ilé Ìṣọ́ February 1
“Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo èèyàn ló ní ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe. Ǹjẹ́ o rò pé Ọlọ́run ń fojú pàtàkì wo ọ̀nà tá a ń gbà sìn ín? [Jẹ́ kó fèsì. Kó o wá ka Mátíù 15:9.] Àpilẹ̀kọ yìí jíròrò ọ̀nà mẹ́rin tí Jésù sọ pé a lè gbà mọ ìsìn tòótọ́.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 16 hàn án.
Ji! January–March
“Ọ̀pọ̀ nǹkan la máa ń gbọ́ pé ó fà á táwọn ìdílé kan fi ń tú ká. Àmọ́, ǹjẹ́ o tiẹ̀ ti fìgbà kan ronú nípa ohun tó mú káwọn ìdílé kan wà ní ìṣọ̀kan? [Jẹ́ kó fèsì.] Ohun tó mú kí àwọn ìdílé kan ṣera wọn lọ́kan ni pé wọ́n ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó wúlò tó wà nínú Bíbélì.” [Ka Kólósè 3:13.] Lẹ́yìn náà, fi àwọn àpilẹ̀kọ tó sọ ohun méje tó lè mú kí ìdílé wà níṣọ̀kan hàn án, bó ṣe wà nínú Jí! yìí.
Ilé Ìṣọ́ March 1
“Ṣé o gbà pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì, àbí o rò pé ó kàn jẹ́ ìwé dáradára kan ni? [Jẹ́ kó fèsì.] Gbọ́ ohun tí Bíbélì fúnra rẹ̀ sọ. [Ka 2 Timothy 3:16, 17.] Ìwé ìròyìn yìí jíròrò àwọn nǹkan tó máa jẹ́ kéèyàn lè ṣe ìpinnu tó tọ́ lórí ọ̀rọ̀ yìí àti ìdí tó fi ṣe pàtàkì láti ṣe bẹ́ẹ̀.”
Ji! January–March
“Ọ̀pọ̀ èèyàn rò pé ó dáa kí ọkùnrin àti obìnrin kọ́kọ́ máa gbé pọ̀ kí wọ́n tó ṣe àdéhùn láti di tọkọtaya. Kí lèrò rẹ? [Jẹ́ kó fèsì. Kó o wá ka 1 Tẹsalóníkà 4:3.] Bíbélì sọ pé kò yẹ kí ọkùnrin àti obìnrin kọ́kọ́ máa gbé pọ̀, ì báà tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣì máa ṣègbéyàwó tó bá yá.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 22 hàn án.