Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ March 8
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MARCH 8
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 1 Sámúẹ́lì 1-4
No. 1: 1 Sámúẹ́lì 2:18-29
No. 2: Kí Ni Ṣọ́ọ̀ṣì Kristẹni Túmọ̀ Sí? (td 43A)
No. 3: Ìwé Mímọ́ Fi Hàn Pé Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Ọmọdé
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
10 min: Ǹjẹ́ O Máa Ń Gbóhùn Sókè Nígbà Tó O Bá Ń Wàásù? Àsọyé tá a gbé ka ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 109, ìpínrọ̀ 2 sí ìparí orí náà.
20 min: “Fi Hàn Pé O Mọyì Ẹ̀bùn Ọlọ́run Tó Tóbi Jù Lọ.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá jíròrò ìpínrọ̀ 3, sọ ètò tí ìjọ yín ṣe fún pípín àkànṣe ìwé ìkésíni síbi Ìrántí Ikú Kristi. Ní kí aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ kan ṣe àṣefihàn bó ṣe máa lo ìwé ìkésíni náà. Lẹ́yìn náà, ní kó sọ bó ṣe ṣètò àkókò rẹ̀ kó lè ráyè ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ àti àwọn àǹfààní tó ti rí níbẹ̀.