Orin 87
A Ti Di Ọ̀kan Ṣoṣo
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Eegun nínú eegun tèmi,
Òun ara mi; miò tún dá wà mọ́.
Jáà ti fún mi lẹ́nì kejì,
Tó jẹ́ onítèmi.
A ti dọ̀kan; a lè wá da
Ohun tí Jèhófà fẹ́ ká dà.
Ọkùnrin fà mọ́ aya rẹ̀,
A di ìdílé kan.
’Joojúmọ́ laó máa sin Ọlọ́run.
Kó ṣamọ̀nà wa.
Ìfẹ́ wa kò ní kùnà.
Báa ṣe jẹ́jẹ̀ẹ́, bẹ́ẹ̀ ni kó rí.
Káyé wa ní ayọ̀ kó lóyin.
Ká máa bọlá fún Jèhófà,
Kí ìfẹ́ wa má ṣe yẹ̀ láé.
(Tún wo Jẹ́n. 29:18; Oníw. 4:9, 10; 1 Kọ́r. 13:8.)