Orin 115
Bá A Ṣe Lè Ṣe Ọ̀nà Wa Ní Rere
1. Ọ̀rọ̀ Jèhófà ńdùn mọ́ wa.
Ká máa kàá lójúmọ́,
Lóhùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́; ká sì tún máa
Ṣàṣàrò, ká paá mọ́.
Kó lè máa tọ́ ìṣísẹ̀ wa,
Àtohun táó máa sọ.
(ÈGBÈ)
Kàá, kóo ṣàṣàrò, kóo paá mọ́.
Jáà yóò sì bù kún ọ.
Tóo bá ńbáa rìn lójoojúmọ́,
Yóò ṣọ̀nà rẹ níre.
2. Àwọn ọba Ísírẹ́lì,
La pa àṣẹ fún pé:
‘Kí ọba fọwọ́ ara rẹ̀
Kọ Òfin Ọlọ́run.
Kó máa kàá títí ayé rẹ̀,
Kó má bàa rú òfin.’
(ÈGBÈ)
Kàá, kóo ṣàṣàrò, kóo paá mọ́.
Jáà yóò sì bù kún ọ.
Tóo bá ńbáa rìn lójoojúmọ́,
Yóò ṣọ̀nà rẹ níre.
3. Báa ti ńka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,
Ó ńfún wa nírètí.
Kò sídààmú ọkàn fún wa;
Ìgbàgbọ́ wa dọ̀tun.
Báa bá fara mọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀,
Òótọ́ yóò máa yé wa.
(ÈGBÈ)
Kàá, kóo ṣàṣàrò, kóo paá mọ́.
Jáà yóò sì bù kún ọ.
Tóo bá ńbáa rìn lójoojúmọ́,
Yóò ṣọ̀nà rẹ níre.
(Tún wo Diu. 17:18; 1 Ọba 2:3, 4; Sm. 119:1; Jer. 7:23.)