Orin 105
Bíi Ti Orí Ìwé
Àwọn Ọ̀run Ń Polongo Ògo Ọlọ́run
(Sáàmù 19)
1. Àwọn ọ̀run ńsọ̀rọ̀ ògo Jèhófà.
A ńríṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀
lójú òfuurufú.
Ojúmọ́ tó ńmọ́ ńfìyìn tó yẹ fúnun.
Ìràwọ̀ ńkéde ògo òun
Ọlá rẹ̀ ní sánmà.
2. Òfin Jèhófà pé, ó fúnni níyè.
Ìránnilétí rẹ̀
ń tọ́ tàgbà tèwe.
Ìdájọ́ rẹ̀ tọ́, òdodo sì ni.
Ọ̀rọ̀ rẹ̀, òfin rẹ̀ dájú,
Ó sì ńdùn ní ahọ́n.
3. Ìbẹ̀rù Ọlọ́run mọ́, ó wà láéláé.
Àṣẹ rẹ̀ ju wúrà
ṣíṣeyebíye lọ.
Òfin rẹ̀ ńtọ́ni, ó ńpàwọn tiẹ̀ mọ́.
A ńgbé ọlá, òkìkí òun
Oókọ mímọ́ rẹ̀ ga.
(Tún wo Sm. 111:9; 145:5; Ìṣí. 4:11.)