ORIN 159
Jèhófà Ni Ìyìn àti Ògo Yẹ!
1. Jèhófà ta ló dà bí rẹ?
Ta ni mo lè fi ọ́ wé?
Títóbi rẹ ga ju ọ̀run,
Ògo àtagbára rẹ pọ̀.
Kí ni mo jẹ́ Ọlọ́run mi,
Tí o fi ń fiyè sí mi?
Kí ni màá fi san oore rẹ,
Fún ìfẹ́ tó ò ń fi hàn sí mi?
(ÈGBÈ)
Ẹnu mi yóò máa kọ orin sí ọ.
Jèhófà jọ̀ọ́ gbóhùn mi.
Ọlọ́run mi Ọba Ayérayé,
Ògo àtìyìn yẹ ọ́;
Màá yìn ọ́ títí ayé.
2. Mo fayé mi fún ọ Bàbá,
Mo fẹ́ máa múnú rẹ dùn.
Màá fayọ̀ wàásù ọ̀rọ̀ rẹ,
Màá ròyìn àwọn oore rẹ.
Àǹfààní ńlá ló jẹ́ fún mi
Pé mo jẹ́ ẹlẹ́rìí rẹ.
Ìwọ ni ibi ààbò mi,
Títí láé ní màá ṣèfẹ́ rẹ.
(ÈGBÈ)
Ẹnu mi yóò máa kọ orin sí ọ.
Jèhófà jọ̀ọ́ gbóhùn mi.
Ọlọ́run mi Ọba Ayérayé,
Ògo àtìyìn yẹ ọ́;
Màá yìn ọ́ títí ayé.
3. Àwọn ohun tí o ṣẹ̀dá
Sáyé àtojú ọ̀run
Jẹ́ kí n rí i pé o nífẹ̀ẹ́ mi,
Àti pé ọgbọ́n rẹ pọ̀ gàn-an.
Àgbàyanu ni iṣẹ́ rẹ,
Ó ń jẹ́ kí orí mi wú!
Ta ni ǹbá tún fì ìyìn fún,
Bí kò ṣèwọ Ẹlẹ́dàá mi?
(ÈGBÈ)
Ẹnu mi yóò máa kọ orin sí ọ.
Jèhófà jọ̀ọ́ gbóhùn mi.
Ọlọ́run mi Ọba Ayérayé,
Ògo àtìyìn yẹ ọ́;
Màá yìn ọ́ títí ayé.
(Tún wo Sm. 96:1-10; 148:3, 7.)