Orin 102
Dara Pọ̀ Nínú Kíkọ Orin Ìjọba Náà!
1. Orin kan rèé, orin ayọ̀ ìṣẹ́gun;
Ọ̀gá Ògo lẹni tó ńgbé lékè.
Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ńmú ká nírètí tó dájú.
Wá ká jọ kọọ́; ohun tó dá lé ni:
(ÈGBÈ)
‘Ẹ wá sin Jáà, Ẹ tẹrí ba.
Jésù jọba; Ẹ kéde rẹ̀!
Wá morin yìí, orin nípa Ìjọba;
Wólẹ̀ fún Jáà, yin oókọ mímọ́ Rẹ̀.’
2. A ńforin tuntun yìí kéde Ìjọba.
Kristi Jésù yóò ṣàkóso ayé.
Àsọtẹ́lẹ̀ wà pé aó bí ilẹ̀ kan:
Ajogún tí yóò fara mọ́ Jésù:
(ÈGBÈ)
‘Ẹ wá sin Jáà, Ẹ tẹrí ba.
Jésù jọba; Ẹ kéde rẹ̀!
Wá morin yìí, orin nípa Ìjọba;
Wólẹ̀ fún Jáà, yin oókọ mímọ́ Rẹ̀.’
3. Orin ’jọba yìí rọrùn fónírẹ̀lẹ̀.
Ọ̀rọ̀ rẹ̀ dùn, ó sì ṣe kedere.
Kárí ayé ogunlọ́gọ̀ ńkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀,
Àwọn pẹ̀lú sì ńpe àwọn mìíràn:
(ÈGBÈ)
‘Ẹ wá sin Jáà, Ẹ tẹrí ba.
Jésù jọba; Ẹ kéde rẹ̀!
Wá morin yìí, orin nípa Ìjọba;
Wólẹ̀ fún Jáà, yin oókọ mímọ́ Rẹ̀.’
(Tún wo Sm. 95:6; 1 Pét. 2:9, 10; Ìṣí. 12:10.)