Orin 15
Ìṣẹ̀dá Ń Ṣí Ògo Jèhófà Payá
Bíi Ti Orí Ìwé
(Sáàmù 19)
1. Ọkàn mi mọ̀, Jèhófà Ọlọ́run.
Ẹgbàágbèje ’ràwọ̀ ńfògo rẹ hàn.
Tọ̀sán-tòru ni wọ́n fi ń sọ̀rọ̀,
Láìfọhùn ni wọ́n ńkọ́ onírẹ̀lẹ̀.
Tọ̀sán-tòru ni wọ́n fi ń sọ̀rọ̀,
Láìfọhùn ni wọ́n ńkọ́ onírẹ̀lẹ̀.
2. O dá oòrùn òṣùpá, ìràwọ̀.
Òkun ńláńlá kò kọjá ààlà wọn.
A wo ọ̀run, sánmà lọ salalu.
Ó yà wá lẹ́nu póo rántí èèyàn.
A wo ọ̀run, sánmà lọ salalu.
Ó yà wá lẹ́nu póo rántí èèyàn.
3. Mímọ́ lòfin rẹ, ìlànà rẹ tọ́.
’Joojúmọ́ nìránnilétí rẹ ńwá.
Wọ́n ju wúrà, wọ́n ńsọ wá dọlọ́gbọ́n.
Aó máa pa wọ́n mọ́, aó dìrọ̀ mọ́ wọn.
Wọ́n ju wúrà, wọ́n ńsọ wá dọlọ́gbọ́n.
Aó máa pa wọ́n mọ́, aó dìrọ̀ mọ́ wọn.
(Tún wo Sm. 12:6; 89:7; 144:3; Róòmù 1:20.)