Orin 26
Bá Ọlọ́run Rìn!
Bíi Ti Orí Ìwé
(Míkà 6:8)
1. Bá Ọlọ́run rìn nírẹ̀lẹ̀;
Nífẹ̀ẹ́ sí òdodo.
Dìwà títọ́ rẹ mú ṣinṣin;
Kí Jáà fún ọ lókun.
Kóo má bàa pàdánù òótọ́,
Má jẹ́ kéèyàn tàn ọ́;
Jẹ́ kí Ọlọ́run fàọ́ lọ́wọ́,
Bí ọmọ kékeré.
2. B’Ọ́lọ́run rìn níwà mímọ́;
Má jìn sọ́fìn ẹ̀ṣẹ̀.
Tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí,
Kóo rójú rere rẹ̀.
Ohunkóhun tíí ṣe mímọ́,
Òótọ́ àtòdodo,
Ni kóo máa rò; nífaradà,
Gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run.
3. B’Ọ́lọ́run rìn nínú òótọ́,
Ìwọ yóò sì wá ní
Ìtẹ́lọ́rùn, ìfọkànsìn,
Tíí ṣe èrè ńlá.
B’Ọ́lọ́run rìn pẹ̀lú ayọ̀
Máa kọrin ìyìn rẹ̀.
Ayọ̀ gíga jù lọ niṣẹ́,
’Jọba rẹ̀ yóò mú wá.
(Tún wo Jẹ́n. 5:24; 6:9; Fílí. 4:8; 1 Tím. 6:6-8.)