Orin 117
A Gbọ́dọ̀ Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Jèhófà
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Ẹ fìdùnnú wá, kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà.
Ẹ̀mí ńsọ wí pé: “Wá gbomi ìyè.”
Ọlọ́run ńkọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ àtàtà.
Oúnjẹ àjẹyó fébi òótọ́ wà.
2. Ẹ má ṣe máa kọ ìpéjọ ará sílẹ̀,
A gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Jèhófà.
Ń’pasẹ̀ ẹ̀mí rẹ̀, àtàwọn ará,
Nípasẹ̀ wọn la ń rí okun gbà.
3. Ètè tó ńkọrin ìyìn ńgbéni ró púpọ̀!
Ahọ́n tí Jáà kọ́ dùn láti gbọ́ gan-an!
Ǹjẹ́ ká máa bá ìjọ Ọlọ́run pé.
Ǹjẹ́ ká wà láàárín wọn nígbà gbogbo.
(Tún wo Héb. 10:24, 25; Ìṣí. 22:17.)