Àwọn Kókó Inú Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn
Inú wa dùn láti sọ fún yín pé ìròyìn tó dáa gan-an la fi bẹ̀rẹ̀ ọdún iṣẹ́ ìsìn tuntun! Iye àwọn akéde tó ròyìn lóṣù September 2009 jẹ́ ẹgbàá méjìdínláàádọ́jọ ó lé mẹ́tàlélọ́gọ́ta [296,063]. Èyí fi ẹgbẹ̀rún mọ́kànlá ó lé òjìlélẹ́gbẹ̀ta [11,640] ju iye àwọn tó ròyìn lóṣù September ọdún 2008 lọ.