Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a máa lò ní February: Ẹ lè lo Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé tàbí Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà. March: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Kí àwọn akéde ní in lọ́kàn láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí onílé bá gba ìwé yìí tàbí tó bá ti ní in lọ́wọ́. April àti May: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tó fìfẹ́ hàn tó fi mọ́ àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi tàbí àwọn àpéjọ míì tí ètò Ọlọ́run ṣètò àmọ́ tí wọn kò tíì máa dara pọ̀ mọ́ ìjọ déédéé, ẹ fún wọn ní ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Kẹ́ ẹ sì ní in lọ́kàn láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wọn.