Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ March 1
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MARCH 1
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Rúùtù 1-4
No. 1: Rúùtù 3:1-13
No. 2: Bá A Ṣe Ń Jàǹfààní Nínú Jíjẹ́ Aláàánú (Mát. 5:7)
No. 3: Àkókò Wo Ni Àwọn Ìgbà Kèfèrí Dópin? (td 30A)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
10 min: Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Sọ ọjọ́ tó kàn tí ìjọ yín máa bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn èèyàn lákànṣe. Sọ àwọn ìrírí tó ń gbéni ró, kó o sì fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu akéde kan nípa ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó rí i pé ó gbéṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. Ní kó ṣe àṣefihàn ọ̀kan lára àwọn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó wà lójú ìwé 5 nínú ìwé Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, lábẹ́ àkọlé náà “Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Inú Ilé.”
10 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
10 min: Ìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì Pé Ká Máa Fi Ìdánilójú Sọ̀rọ̀ Lẹ́nu Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 194 sí 196.