Orin 10
“Èmi Nìyí! Rán Mi”
1. Ayé ńkẹ́gàn òun ìtìjú,
Bá oókọ ògo Ọlọ́run.
Ẹlòmíì ńpèé ní òǹrorò.
Òpònú ní: “Kò s’Ọ́lọ́run!”
Ta ni yóò lọ kéde òótọ́?
Táá máa yin oókọ Ọlọ́run?
‘Olúwa, Èmi rèé! Rán mi.
Nó fòótọ́ kọrin ìyìn rẹ.
(Ègbè)
Ọlá kan kò jùyí, Olúwa.
Èmi rèé! Rán mi, rán mi.’
2. Ẹ̀dá ńsọ p’Ọ́lọ́run lọ́ra;
Wọn kò níbẹ̀rù Ọlọ́run.
Wọ́n ńbọ̀rìṣà, bọgi, bọ̀pẹ̀;
Késárì di Ọlọ́run wọn.
Ta ni yóò kìlọ̀ fẹ́ni’bi?
Táá kìlọ̀ Amágẹ́dọ́nì?
‘Olúwa, Èmi rèé! Rán mi.
Nó kìlọ̀ fún wọn láìbẹ̀rù.
(Ègbè)
Ọlá kan kò jùyí, Olúwa.
Èmi rèé! Rán mi, rán mi.’
3. Lónìí onírẹ̀lẹ̀ ńkẹ́dùn
Torí ibi túbọ̀ ńpọ̀ síi.
Wọ́n ńfi ọkàn mímọ́ wádìí
Òótọ́ táá fọkàn wọn balẹ̀.
Ta ni yóò mútùnú tọ̀ wọ́n?
Táá tọ́ wọn sọ́nà òdodo?
‘Olúwa, Èmi rèé! Rán mi.
Nó fi sùúrù kọ́ ońrẹ̀lẹ̀.
(ÈGBÈ)
Ọlá kan kò jùyí, Olúwa.
Èmi rèé! Rán mi, rán mi.’