Orin 145
À Ń Múra Láti Lọ Wàásù
Bíi Ti Orí Ìwé
Ilẹ̀ mọ́.
Láìpẹ́, a máa
Jáde lọ sóde ẹ̀rí.
Àmọ́ òjò ṣú,
Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀.
Ó lè wù wá ká dúró sílé,
ká sì sùn.
(ÈGBÈ)
Èrò tó tọ́, ìmúrasílẹ̀,
Àtàdúrà gbígbà;
Ìwọ̀nyí lè fún wa ní okun,
Tí a nílò.
Àwọn áńgẹ́lì wà lẹ́yìn wa.
Jésù ló ń darí wọn.
Pẹ̀lú ẹni tá a jọ máa ṣiṣẹ́,
A ó ṣe é yọrí.
A ó rí i pé
A máa láyọ̀
Tá a bá fi nǹkan yìí sọ́kàn.
Jèhófà sì ń rí
Gbogbo ipá tá à ń sà,
A mọ̀ pé kò ní gbàgbé ìfẹ́;
tá a fi hàn.
(ÈGBÈ)
Èrò tó tọ́, ìmúrasílẹ̀,
Àtàdúrà gbígbà;
Ìwọ̀nyí lè fún wa ní okun,
Tí a nílò.
Àwọn áńgẹ́lì wà lẹ́yìn wa.
Jésù ló ń darí wọn.
Pẹ̀lú ẹni tá a jọ máa ṣiṣẹ́,
A ó ṣe é yọrí.
(Tún wo Oníw. 11:4; Mát. 10:5, 7; Lúùkù 10:1; Títù 2:14.)