Orin 150
Wá Wọn Lọ
Bíi Ti Orí Ìwé
Jèhófà mọ ohun tó máa
Jẹ́ ká láyọ̀, káyé yẹ wá.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àǹfààní wà
Ká fayé wa sin Ọlọ́run.
(ÈGBÈ)
Wá wọn lọ, sapá gan-an,
ṣiṣẹ́ Ọlọ́run.
Sìn níbi tí àìní pọ̀ sí gan-an,
fìfẹ́ wá wọn lọ.
Kò síbi tí iṣẹ́ kò sí.
Níbi àìní, lọ ṣèrànwọ́.
Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a nífẹ̀ẹ́ wọn.
Ká lọ síbẹ̀, ká lọ wàásù.
(ÈGBÈ)
Wá wọn lọ, sapá gan-an,
ṣiṣẹ́ Ọlọ́run.
Sìn níbi tí àìní pọ̀ sí gan-an,
fìfẹ́ wá wọn lọ.
Tó ò bá lè lọ, níbi tó o wà,
Múra sílẹ̀, máa sunwọ̀n sí i.
Sapá láti kọ́ èdè mí ì
Kó o lè wàásù f’ọ́pọ̀ èèyàn.
(ÈGBÈ)
Wá wọn lọ, sapá gan-an,
ṣiṣẹ́ Ọlọ́run.
Sìn níbi tí àìní pọ̀ sí gan-an,
fìfẹ́ wá wọn lọ.
(Tún wo Jòh. 4:35; Ìṣe 2:8; Róòmù 10:14.)