Orin 140
Ìgbé Ayé Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà
Ní òwúrọ̀ kùtù, tí oòrùn kò tí ì yọ,
À ń jáde lọ wàásù
oorun wà lójú wa,
à ń bẹ Jáà.
À ń rẹ́rìn-ín músẹ́ sáwọn èèyàn tá a pàdé.
Àwọn kan gbọ́rọ̀ wa,
àwọn mí ì kò fẹ́ gbọ́, kò sú wa.
(ÈGBÈ)
Iṣẹ́ tá a fẹ́ nìyẹn;
Ti Jèhófà la jẹ́.
Gbogbo ohun tó fẹ́ la ó máa ṣe.
Nípòkípò tá a wà,
A ó máa fara dà á lọ.
Èyí la fi lè sọ pé:
“A nífẹ̀ẹ́ rẹ gan-an.”
Ní ọwọ́ ìrọ̀lẹ́, tí oòrùn bá ti ń wọ̀,
Pẹ̀lú bó ṣe rẹ̀ wá,
inú wa ń dùn,
a sì tún ń dúpẹ́.
À ń fayé wa sin Jáà, èyí sì ń dùn mọ́ wa.
À ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀,
Ojoojúmọ́ ló máa ń bù kún wa.
(ÈGBÈ)
Iṣẹ́ tá a fẹ́ nìyẹn;
Ti Jèhófà la jẹ́.
Gbogbo ohun tó fẹ́ la ó máa ṣe.
Nípòkípò tá a wà,
A ó máa fara dà á lọ.
Èyí la fi lè sọ pé:
“A nífẹ̀ẹ́ rẹ gan-an.”
(Tún wo Jóṣ. 24:15; Sm. 92:2; Róòmù 14:8.)