Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí la máa fi ṣàtúnyẹ̀wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run lọ́sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní February 22, 2010. Àtúnyẹ̀wò yìí dá lórí àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tá a ṣe láàárín ọ̀sẹ̀ January 4 sí February 22, 2010, alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ á sì darí rẹ̀ fún ogún [20] ìṣẹ́jú.
1. Irú ẹ̀mí wo ló yẹ ká ṣọ́ra fún? (Jóṣ. 22:9-12, 21-33) [w04 12/1 ojú ìwé 12, ìpínrọ̀ 3]
2. Kí lohun náà gan-an tó mú kí Jóṣúà sọ ohun tó sọ nínú Jóṣúà 24:14, 15, ipa wo ló sì yẹ kí ìyẹn ní lórí wa? [w08 5/15 ojú ìwé 17 sí 18, ìpínrọ̀ 4 sí 6]
3. Ọ̀nà wo ni àwọn olùjọ́sìn Báálì àti ìjọsìn wọn gbà di ìdẹkùn àti ohun adẹnilọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì? (Oníd. 2:3) [w08 2/15 ojú ìwé 27, ìpínrọ̀ 1 sí 2]
4. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú bí Éhúdù ṣe fìgboyà lo idà? (Oníd. 3:16, 21) [w97 3/15 ojú ìwé 31, ìpínrọ̀ 4]
5. Ìṣírí wo la rí gbà látinú kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Jèhófà ṣe gba Gídíónì àtàwọn ọ̀ọ́dúnrún [300] ọkùnrin rẹ̀ là? (Oníd. 7:19-22) [w05 7/15 ojú ìwé 16, ìpínrọ̀ 8]
6. Ọ̀nà wo ni ọkàn Jèhófà “kò fi lélẹ̀ nítorí ìdààmú Ísírẹ́lì”? (Oníd. 10:16) [cl ojú ìwé 254 sí 255, ìpínrọ̀ 10 sí 11]
7. Nígbà tí Jẹ́fútà ń jẹ́jẹ̀ẹ́, ṣé ó ní in lọ́kàn láti fi èèyàn rúbọ ni? (Oníd. 11:30, 31) [w05 1/15 ojú ìwé 26, ìpínrọ̀ 1]
8. Ṣé inú irun orí Sámúsìnì gan-gan ni agbára rẹ̀ wà? (Oníd. 16:18-20) [w05 3/15 ojú ìwé 28, ìpínrọ̀ 5 sí 6]
9. Ìrànlọ́wọ́ wo ló máa ṣe fún wa tá a bá lóye ohun àgbàyanu tí Sámúsìnì ṣe, gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Onídàájọ́ 16:3? [w04 10/15 ojú ìwé 15 sí 16, ìpínrọ̀ 7 sí 8]
10. Kí la lè rí kọ́ nípa ọkàn látinú gbólóhùn tó wà nínú Onídàájọ́ 16:30? [w90 9/1 ojú ìwé 5, ìpínrọ̀ 4; sp ojú ìwé 13 sí 14]