Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ February 22
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ FEBRUARY 22
Orin 191
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Àwọ̀n Onídàájọ́ 19-21
Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
10 min: Ìwé Tá A Máa Lò Lóṣù March. Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu akéde méjì, ní kí wọ́n ṣàlàyé àwọn kókó pàtàkì tá a lè lò lóde ẹ̀rí nínú ìwé tá a máa lò lóṣù March àti ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tí wọ́n ti rí i pé ó gbéṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. Ní kí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ṣàṣefihàn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ kan tàbí kí wọ́n ṣe àṣefihàn ìrírí kan tó fi hàn bí wọ́n ṣe lo ìwé náà láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
10 min: Fífi Èrò Wérò Máa Ń Mú Káwọn Èèyàn Fetí Sílẹ̀. Àsọyé tá a gbé ka ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 251 sí ojú ìwé 253, ìpínrọ̀ 1.
10 min: “Bá A Ṣe Lè Pe Àwọn Olùfìfẹ́hàn Wá Sínú Ètò Jèhófà.” Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tó dá lé àwọn ìpínrọ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tó wà lábẹ́ ìsọ̀rí ojú ìwé 99 nínú ìwé A Ṣètò Wa. Béèrè lọ́wọ́ àwọn ará bí wọ́n ti ṣe darí àwọn olùfìfẹ́hàn sínú ètò Jèhófà. Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu akéde kan tó jàǹfààní látàrí bí ẹni tó kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe darí rẹ̀ sínú ètò Jèhófà.