“Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn”
1. Àǹfààní wo la máa ní ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ láwọn oṣù tó ń bọ̀?
1 Ohun táwọn ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sọ nípa ìgbé ayé Jésù nígbà tó wà láyé jẹ́ ká mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ irú ẹni tí Ọmọ Ọlọ́run jẹ́. Níwọ̀n bí àwa Kristẹni ti gbọ́dọ̀ “tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí,” á dáa ká múra sílẹ̀ dáadáa ká sì máa fọkàn bá a lọ bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ ìwé náà, “Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn” ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀sẹ̀ March 1. (1 Pét. 2:21; Máàkù 10:21) Ó yẹ ká fún àwọn apá ìgbé ayé Jésù tó lè fún wa níṣìírí lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa láfiyèsí àrà ọ̀tọ̀.
2. Báwo la ṣe lè jàǹfààní látinú àpẹẹrẹ ìfaradà Jésù?
2 Àpẹẹrẹ Tí Jésù Fi Lélẹ̀: Ǹjẹ́ ó ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ rí pé àwọn èèyàn ò fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ nígbà tó ò ń wàásù láti ilé dé ilé? Bó bá ṣẹlẹ̀ pé àwọn èèyàn kò fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ wa, ohun tó máa ń wá sí wa lọ́kàn ni ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé: “Bí wọ́n bá ti ṣe inúnibíni sí mi, wọn yóò ṣe inúnibíni sí yín pẹ̀lú.” (Jòh. 15:20) Lóòótọ́, kì í ṣe gbogbo ìgbà táwọn èèyàn ò bá fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ wa ni wọ́n ń ṣe inúnibíni sí wa. Ní ti Jésù, ìdùnnú tá a gbé ka iwájú rẹ̀ ló mú kó lè fara da gbogbo onírúurú àdánwò àti ìṣòro tó dojú kọ ọ́. Àwa náà lè fọkàn sí bá a ṣe máa rí ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà àti bó ṣe máa bù kún wa nítorí ìṣòtítọ́ wa. Èyí ni ò ní jẹ́ kó ‘rẹ̀ wá, kí a sì rẹ̀wẹ̀sì nínú ọkàn wa.’ (Héb. 12:2, 3; Òwe 27:11) Bí a ti ń ní ìforítì lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, ó yẹ kó dá wa lójú pé Kristi Jésù ń tì wá lẹ́yìn.—Mát. 28:20.
3. Báwo la ṣe lè máa fi ojú tí Jésù fi wo iṣẹ́ òjíṣẹ́ wò ó?
3 “Tìtorí Èyí Ni A Ṣe Rán Mi Jáde”: Wíwàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run ló gba ipò àkọ́kọ́ ní ìgbésí ayé Jésù. (Lúùkù 4:43) Ó fi ara rẹ̀ jìn pátápátá fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. Ó wò ó bí iṣẹ́ kánjúkánjú, ó sì máa ń lo gbogbo àǹfààní tó bá ṣí sílẹ̀ láti sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run. Níwọ̀n bá a ti jẹ́ ọmọlẹ́yìn Jésù, kí ni títẹ̀lé ìṣísẹ̀ rẹ̀ máa jẹ́ ká ṣe? Bá a ti ń bá ìgbòkègbodò wa ojoojúmọ́ lọ, ǹjẹ́ àwọn kan wà tá a lè wàásù ìhìn rere fún? Ǹjẹ́ kí ìfẹ́ tí Kristi ní sọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún wa láti tan ìhìn rere kálẹ̀ bó bá ti lè ṣeé ṣe tó!—2 Kọ́r. 5:14.
4. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa sunwọ̀n sí i?
4 “Ènìyàn Mìíràn Kò Tíì Sọ̀rọ̀ Báyìí Rí”: Ọ̀nà tí Jésù gbà kọ́ni ya àwọn olùgbọ́ rẹ̀ lẹ́nu. (Jòh. 7:46; Mát. 7:28, 29) Kí ló mú kí Jésù yàtọ̀ sí àwọn olùkọ́ yòókù? Ó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ tó fi kọ́ni, ó nífẹ̀ẹ́ àwọn tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́, ó sì lo oríṣiríṣi ọ̀nà láti fi kọ́ni. Bá a bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Olùkọ́ Ńlá náà, iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa á sunwọ̀n sí i.—Lúùkù 6:40.
5. Kí ló yẹ kó jẹ́ àfojúsùn wa bá a ó ṣe máa kẹ́kọ̀ọ́ ìwé náà “Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn”?
5 Àwọn nǹkan tá a jíròrò wọ̀nyí jẹ́ díẹ̀ lára àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye tí ìgbé ayé Jésù kọ́ wa. Àwọn ẹ̀kọ́ ṣíṣeyebíye míì wo lo tún lè rí kọ́? Bó o ṣe ń ṣàyẹ̀wò ìgbé ayé Jésù nígbà Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ, fi ṣe àfojúsùn rẹ láti “mọ ìfẹ́ Kristi” nípa títẹ̀lé àwọn ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ̀.—Éfé. 3: 19.