Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ February 15
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ FEBRUARY 15
Orin 144
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Àwọn Onídàájọ́ 15-18
No. 1: Àwọn Onídàájọ́ 16:1-12
No. 2: Ṣé Ó Tọ́ Láti Rú Òfin Ọlọ́run Nítorí Àtigba Ẹ̀mí Là? (td 11B)
No. 3: Ìdí Tí Jésù Fi Pe Èṣù Ní “Baba Irọ́” (Jòh. 8:44)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
15 min: Múra Sílẹ̀ Láti Lo Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Ní ṣókí, sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìwé ìròyìn tá a máa lò, kó o sì dábàá àwọn àpilẹ̀kọ tó ṣeé ṣe káwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. Ṣe àṣefihàn bí akéde kan ṣe ń dá nìkan múra sílẹ̀ láti fi àwọn ìwé ìròyìn náà lọni. Ó yan àwọn àpilẹ̀kọ táwọn èèyàn lè nífẹ̀ẹ́ sí ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín, ìbéèrè tó máa lò àti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó máa kà. Lẹ́yìn náà, ó múra ọ̀nà tó máa gbà gbé ọ̀rọ̀ rẹ̀ kalẹ̀ nípa fífi ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìwé ìròyìn náà ṣe ìdánrawò.
15 min: “Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Bó o bá ti parí ìjíròrò yìí, lo ìsọfúnni tó wà lójú ìwé 70 nínú ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run láti rán àwọn ará létí ohun tó yẹ kí wọ́n fi sọ́kàn nípa dídáhùn láwọn ìpàdé ìjọ.
Orin 224