ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • sn orin 28
  • Orin Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Orin Tuntun
  • Kọrin sí Jèhófà
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Orin Tuntun
    “Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà
  • Ìyè Àìnípẹ̀kun Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín!
    “Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà
  • O Fún Wa Ní Ọmọ Rẹ Kan Ṣoṣo
    Kọrin sí Jèhófà—Àwọn Orin Tuntun
  • Ìyè Àìnípẹ̀kun Nígbẹ̀yìngbẹ́yín!
    Kọrin sí Jèhófà
Àwọn Míì
Kọrin sí Jèhófà
sn orin 28

Orin 28

Orin Tuntun

Bíi Ti Orí Ìwé

(Sáàmù 98)

1. Kọrin s’Ọ́lọ́run, Orin ìyìn, orin tuntun.

Sọ̀rọ̀ ohun ńláǹlà Tó ṣe tí yóò sì ṣe.

Yin apá ńlá rẹ̀, Ọlọ́run ìṣẹ́gun ló jẹ́.

Nínú ìdájọ́ rẹ̀, Òdodo ló máa ńṣe.

(ÈGBÈ)

Kọ orin!

Jẹ́ kórin tuntun dún!

Kọ orin!

Jèhófà lọba wa.

2. Hó ìhó ayọ̀ Sí Ọlọ́run, Ọba tiwa!

Fayọ̀ kọrin ìyìn; Tó ńgbórúkọ rẹ̀ ga.

Ẹ jùmọ̀ kọrin, Kó dún níwájú Olúwa.

Kàkàkí òun hàápù,

Kọrin ìyìn pa pọ̀.

(ÈGBÈ)

Kọ orin!

Jẹ́ kórin tuntun dún!

Kọ orin!

Jèhófà lọba wa.

3. Kí ẹ̀dá òkun Àti òkun hó fún ìyìn.

Káwọn tí ńbẹ láyé Gbóhùn ìyìn sókè.

Kínú ilẹ̀ dùn, Káwọn odò sì pàtẹ́wọ́.

Òkè òun pẹ̀tẹ́lẹ̀,

Kọrin kárí ayé.

(ÈGBÈ)

Kọ orin!

Jẹ́ kórin tuntun dún!

Kọ orin!

Jèhófà lọba wa.

(Tún wo Sm. 96:1; 149:1; Aísá. 42:10.)

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́