Orin 127
Ibi Tá A Ń Fi Orúkọ Rẹ Pè
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Ọlá ńlá lo dá wa Jèhófà,
Láti kọ́lé fórúkọ rẹ!
Inú wa dùn láti fi fún ọ
Kí ògo rẹ lè máa pọ̀ síi.
Ohunkóhun yòówù ká fún ọ,
Tìrẹ ni wọ́n tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀.
Ohun gbogbo táa mọ̀ táa sì ní,
Tayọ̀tayọ̀ la yọ̀ǹda wọn.
(ÈGBÈ)
A fẹ́ fi ibí yìí fún ọ
Kórúkọ rẹ wà níbẹ̀.
A yà á sí mímọ́ fún ọ;
Jọ̀wọ́ gbà á tìrẹ ni.
2. Ọlá ńlá la bù fún ọ Baba,
Bí ìyìn rẹ ṣe gbabí kan.
Jẹ́ káwọn tó ńmọ̀ ọ́ máa pọ̀ síi
Ògo rẹ yóò lè máa pọ̀ síi.
Torí ìwọ laó máa sìn níbí,
A ó máa tọjú rẹ̀ dáadáa.
Kó máa jẹ́ ẹ̀rí fáwọn èèyàn,
Kó lè fi kún ìwàásù wa.
(ÈGBÈ)
A fẹ́ fi ibí yìí fún ọ
Kórúkọ rẹ wà níbẹ̀.
A yà á sí mímọ́ fún ọ;
Jọ̀wọ́ gbà á tìrẹ ni.
(Tún wo 1 Ọba 8:18, 27; 1 Kíró. 29:11-14; Ìṣe 20:24.)