Orin 56
Jọ̀wọ́ Gbọ́ Àdúrà Mi
Bíi Ti Orí Ìwé
(Sáàmù 54)
1. Baba ọ̀run, gbóhùn orin mi.
Ọlọ́run mi, tìrẹ ni mo jẹ́.
Orúkọ rẹ tóbi, kò lẹ́gbẹ́.
(ÈGBÈ)
Jọ̀ọ́, Jèhófà gbọ́ àdúrà mi.
2. O ṣeun òní, Baba mi ọ̀run,
O dá mi sí, o ńfọ̀nà hàn mí.
Mo tún dúpẹ́ bóo ṣe ńtọ́jú mi.
(ÈGBÈ)
Jọ̀ọ́, Jèhófà gbọ́ àdúrà mi.
3. Ó ńwù mí gan-an láti ṣe rere!
Jẹ́ kí nlè rìn nínú ìmọ́lẹ̀.
Jọ̀wọ́ fún mi ní ìfaradà.
(ÈGBÈ)
Jọ̀ọ́, Jèhófà gbọ́ àdúrà mi.
(Tún wo Ẹ́kís. 22:27; Sm. 106:4; Ják. 5:11.)