Orin 68
Àdúrà Ẹni Rírẹlẹ̀
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Jèhófà Ọlọ́run, mo pè ọ́:
“Gbọ́ àdúrà mi.”
Ọgbẹ́ ọkàn mi pọ̀ jù;
ẹrù yìí wọ̀ mí lọ́rùn.
Ìbànújẹ́ dorí mi kodò,
ó tán mi lókun.
Ọlọ́run ìtùnú, jọ̀wọ́
ṣíjú àánú wò mí.
(ÈGBÈ)
Gbé mi dìde, fún mi lókun.
Jẹ́ nnírètí, tí nbá mikàn.
Mo sá di ọ́, ń’nú ìdààmú.
Jáà, sọ agbára mi dọ̀tun.
2. Nígbà tó rẹ̀ mí, ọ̀rọ̀ rẹ
nìtùnú àtààbò,
Bó ṣe rí lára mi, ẹnu
mi kò lè ṣàlàyé.
Jọ̀wọ́ jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ rẹ máa
fún mi ní ìgbàgbọ́.
Kí nmáa rántí pé ìfẹ́ rẹ
tóbi ju ọkàn mi.
(ÈGBÈ)
Gbé mi dìde, fún mi lókun.
Jẹ́ nnírètí, tí nbá mikàn.
Mo sá di ọ́, ń’nú ìdààmú.
Jáà, sọ agbára mi dọ̀tun.
(Tún wo Sm. 42:6; 119:28; 2 Kọ́r. 4:16; 1 Jòh. 3:20.)