ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 3/15 ojú ìwé 29-31
  • Éhúdù—Ọkùnrin Ìgbàgbọ́ àti Onígboyà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Éhúdù—Ọkùnrin Ìgbàgbọ́ àti Onígboyà
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ará Móábù Kọlù Wọ́n Lójijì
  • Éhúdù Ṣalábàápàdé Ẹ́gílónì
  • Éhúdù Pa Dà Wá
  • Mímọ Ohun Tí Ó Ṣẹlẹ̀ àti Ìbìṣubú
  • Kíkẹ́kọ̀ọ́ Láti Inú Àpẹẹrẹ Éhúdù
  • Éhúdù Ṣẹ́ Àjàgà Aninilára
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìtàn Tó Ń Mórí Ẹni Wú Nípa Ọkùnrin Onígboyà Kan
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
  • Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Àwọn Onídàájọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 3/15 ojú ìwé 29-31

Éhúdù—Ọkùnrin Ìgbàgbọ́ àti Onígboyà

Ọ̀PỌ̀ ọdún ti kọjá láti ìgbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ́kọ́ fẹsẹ̀ tẹ Ilẹ̀ Ìlérí. Mósè àti agbapò rẹ̀, Jóṣúà, ti kú tipẹ́. Nítorí àìsí irú àwọn ọkùnrin ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀, ìmọrírì fún ìjọsìn mímọ́ gaara dín kù lójijì. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tilẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn Báálì àti àwọn òpó ọlọ́wọ̀.a Nítorí èyí, Jèhófà fi àwọn ènìyàn rẹ̀ lé àwọn ara Síríà lọ́wọ́, fún ọdún mẹ́jọ. Nígbà náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ké pe Ọlọ́run fún ìrànlọ́wọ́. Ó fetí sí wọn tàánútàánú. Jèhófà gbé onídàájọ́ kan dìde, Ótíníẹ́lì, látí dá àwọn ènìyàn Rẹ̀ nídè.—Onídàájọ́ 3:7-11.

Ó yẹ kí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí ti kọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní òkodoro òtítọ́ kan—ìgbọràn sí Jèhófà ń mú ìbùkún wá, ṣùgbọ́n àìgbọràn ń yọrí sí ègún. (Diutarónómì 11:26-28) Ṣùgbọ́n, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kùnà láti kẹ́kọ̀ọ́ àríkọ́gbọ́n yìí. Lẹ́yìn 40 ọdún aláàláfíà, wọ́n pa ìjọsìn mímọ́ gaara tì lẹ́ẹ̀kan sí i.—Onídàájọ́ 3:12.

Àwọn Ará Móábù Kọlù Wọ́n Lójijì

Lọ́tẹ̀ yí, Jèhófà jẹ́ kí àwọn ènìyàn rẹ̀ ṣubú sọ́wọ́ Ọba Ẹ́gílónì ti ilẹ̀ Móábù. Bíbélì ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “ọkùnrin tí ó sanra púpọ̀.” Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ámónì àti Ámálékì, Ẹ́gílónì kọlu Ísírẹ́lì, ó sì kọ́ ààfin rẹ̀ sí Jẹ́ríkò, “ìlú ọ̀pẹ.” Ẹ wo bí ó ti takora tó pé ìlú àwọn ara Kénáánì àkọ́kọ́ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun, wá di orílé-iṣẹ́ ẹni tí ń jọ́sìn ọlọ́run èké náà, Kémóṣì!b—Onídàájọ́ 3:12, 13, 17.

Ẹ́gílónì ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lára fún ọdún 18 tí ó tẹ̀ lé e, tí ó ṣe kedere pé, ó ń fi agbára béèrè owó orí tí ó ni wọ́n lára lọ́wọ́ wọn. Nípa bíbéèrè fún owó òde lóòrèkóòrè, Móábù mú ọrọ̀ ajé rẹ̀ lágbára sí i, bí ó ti ń fa ohun àmúṣọrọ̀ Ísírẹ́lì gbẹ. Abájọ tí àwọn ènìyàn Ọlọ́run fi kígbe fún ìtura, Jèhófà sì tẹ́tí sí wọn lẹ́ẹ̀kan sí i. Ó gbé olùgbàlà míràn dìde fún wọn—lọ́tẹ̀ yí, ọmọ ìran Bẹ́ńjámínì kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Éhúdù. Láti mú òpin dé bá ìwà òṣìkà agbonimọ́lẹ̀ tí Ẹ́gílónì ń hù sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, Éhúdù wéwèé láti gbé ìgbésẹ̀ ní ọjọ́ tí wọn yóò lọ san owó òde tí ó tẹ̀ lé e.—Onídàájọ́ 3:14, 15.

Láti múra sílẹ̀ fún ìgbésẹ̀ rẹ̀ yí tí ó gba ìgboyà, Éhúdù rọ idà olójú méjì, tí ó gùn ní ìgbọ̀nwọ́ kan. Bí èyí bá jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kúkúrú, ohun ìjà náà kò ní ju sẹ̀ǹtímítà 38 lọ ní gígùn. Àwọn ẹlòmíràn yóò kà á sì ọ̀bẹ aṣóró. Ó ṣe kedere pé, kò sí ohunkóhun tí ó dábùú abẹ idà náà àti èèkù rẹ̀. Nítorí náà, Éhúdù lè fi idà kékeré rẹ̀ pa mọ́ sí abẹ́ ẹ̀wù rẹ̀. Síwájú sí i, níwọ̀n bí Éhúdù ti jẹ́ ọlọ́wọ́ òsì, ó lè sán idà rẹ̀ sí apá ọ̀tún rẹ̀—ibi tí a kì í sábà fi ohun ìjà sí.—Onídàájọ́ 3:15, 16.

Ìwéwèé àfìṣọ́raṣe Éhúdù kò ṣàìmú ewu lọ́wọ́. Fún àpẹẹrẹ, bí àwọn ẹmẹsẹ̀ ọba bá yẹ ara Éhúdù wò láti mọ̀ bóyá ohun ìjà wà níbẹ̀ ńkọ́? Bí wọn kò bá tilẹ̀ ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé wọn kò ní fi ọmọ Ísírẹ́lì nìkan sílẹ̀ pẹ̀lú ọba wọn! Ṣùgbọ́n, bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, tí ó sì ṣeé ṣe láti pa Ẹ́gílónì, báwo ni Éhúdù yóò ṣe sá lọ? Ibo ni yóò sáré dé kí àwọn ẹmẹsẹ̀ Ẹ́gílónì tó mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀?

Kò sí àníàní pé, Éhúdù ti sinmẹ̀dọ̀ ronú lórí àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ wọ̀nyí, tí ó sì ṣeé ṣe kí ó ti finú wòye onírúurú àbájáde oníjàǹbá tí ó lè jẹ yọ. Bí ó ti wù kí ó rí, ó tẹ̀ síwájú pẹ̀lú ìwéwèé rẹ̀, ní fífi ìgboyà àti ìgbàgbọ́ hàn nínú Jèhófà.

Éhúdù Ṣalábàápàdé Ẹ́gílónì

Ọjọ́ tí wọn yóò gbé owó òde mìíràn wá kò. Éhúdù àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ wọ ààfin ọba lọ. Kò pẹ́ kò jìnnà, wọ́n dúró níwájú Ọba Ẹ́gílónì fúnra rẹ̀. Ṣùgbọ́n, àkókò kò tí ì tó fún Éhúdù láti kọlu Ẹ́gílónì. Lẹ́yìn tí wọ́n gbé owó òde náà fún ọba, Éhúdù rán àwọn tí ó ru owó òde náà wá pa dà sílé.—Onídàájọ́ 3:17, 18.

Èé ṣe tí Éhúdù kò fi tètè kọlu Ẹ́gílónì? Ẹ̀rù ha ń bà á bí? Kí a má rí i! Láti mú ìwéwèé rẹ̀ ṣẹ, Éhúdù ní láti wà ní òun nìkan pẹ̀lú ọba—ohun kan tí a kò gbà á láyè láti ṣe nígbà ìbẹ̀wò àkọ́kọ́ yìí. Síwájú sí i, Éhúdù yóò ní láti wá ọ̀nà àbájáde tí yóò yá kíákíá. Sísálọ yóò rọrùn púpọ̀ fún ẹnì kan ṣoṣo jù fún gbogbo ikọ̀ tí ó gbé owó òde wá. Nítorí náà, Éhúdù fi sùúrù dúró de àkókò tí ó rọgbọ. Ìbẹ̀wọ̀ ráńpẹ́ tí ó ṣe sí Ẹ́gílónì mú kí ó ṣeé ṣe fún un láti mọ tinútòde ààfin náà dáradára, kí ó sì lè mọ bí ààbò ọba ti pọ̀ tó.

Lẹ́yìn dídé “ibi ère fínfín tí ó wà létí Gílígálì,” Éhúdù fi àwọn ọkùnrin rẹ̀ sílẹ̀, ó sì rìnrìn àjò pa dà sí ààfin Ẹ́gílónì. Ìrìn tí ó tó nǹkan bíi kìlómítà méjì tí Éhúdù rìn, fún un ní àkókò díẹ̀ láti ronú lórí iṣẹ́ tí ó ní lọ́wọ́ láti ṣe, àti láti gbàdúrà fún ìbùkún Jèhófà.—Onídàájọ́ 3:19.

Éhúdù Pa Dà Wá

Ó ṣe kedere pé a gba Éhúdù tọwọ́ tẹsẹ̀ pa dà sínú ààfin. Bóyá owó òde rẹpẹtẹ tí ó ti gbé wá ṣáájú mú inú Ẹ́gílónì yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀. Ó lè jẹ́ pé, bí ìbẹ̀wò àkọ́kọ́ tilẹ̀ kúrú, ó fún Éhúdù ní àǹfààní tí ó pọ̀ tó láti fìdí ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú ọba múlẹ̀. Ohun yòó wù kí ó jẹ́, Éhúdù ti pa dà síwájú Ẹ́gílónì.

Éhúdù sọ pé: “Ọba, mo ní ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ kan í bá ọ sọ.” Òtítọ́ náà pé, ó dé ibi tí ó dé yìí jẹ́ ẹ̀rí pé Jèhófà ń ṣamọ̀nà rẹ̀. Síbẹ̀, ìṣòro kan wà. “Ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀” tí Éhúdù fẹ́ sọ, kò ṣeé sọ níwájú àwọn ẹmẹsẹ̀ ọba. Bí Jèhófà yóò bá dá sí ọ̀rọ̀ náà, ní lọ́ọ́lọ́ọ́ báyìí ni Éhúdù nílò ìrànlọ́wọ́ náà. Ọba náà pàṣẹ pé: “Ẹ dákẹ́.” Níwọ̀n bí Ẹ́gílónì kò ti fẹ́ kí “ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀” yí di èyí tí ó ta síta, ó rán àwọn ẹmẹsẹ̀ rẹ̀ jáde. Ẹ wó bí inú Éhúdù yóò ti dùn tó!—Onídàájọ́ 3:19.

Ẹ́gílónì jókòó nínú ìyẹ̀wù òrùlé rẹ̀ nígbà tí Éhúdù tọ̀ ọ́ wá, tí ó sì wí pé: “Mo ní ọ̀rọ̀ kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá fún ọ.” Nígbà tí ó sọ pé, “Ọlọ́run,” Kémóṣì ha ni Éhúdù ń sọ bí? Ó ṣeé ṣe kí Ẹ́gílónì ti rò bẹ́ẹ̀. Bí ọ̀rọ̀ náà ti ru ú lọ́kàn sókè, ó dìde lórí ìtẹ́ rẹ̀, ó fi ìháragàgà dìde dúró. Éhúdù sún mọ́ ọn, bóyá ó ń rọra rìn, kí ọba má baà fura pé ó fẹ́ kọlu òun. Lẹ́yìn náà, pẹ̀lú ìyárakánkán, “Éhúdù sì na ọwọ́ òsì rẹ̀, ó sì yọ idà náà kúrò ní itan ọ̀tún rẹ̀, ó sì fi gún [Ẹ́gílónì] ní ikùn. Àti idà àti èèkù sì wọlé; Ọ̀rá sì bo ìdà náà nítorí tí kò fa idà náà yọ kúrò nínú ikùn rẹ̀; ó sì yọ lẹ́yìn.”—Onídàájọ́ 3:20-22.

Bí wọ́n tilẹ̀ ń fẹsẹ̀ palẹ̀ kiri nítòsí, àwọn ẹmẹsẹ̀ ọba kò yọjú. Ṣùgbọ́n ẹ̀mí Éhúdù ṣì wà nínú ewu síbẹ̀. Àwọn ìránṣẹ́ Ẹ́gílónì lè rọ́ wọlé nígbàkugbà, kí wọ́n sì rí òkú ọba wọn tí ó ti ṣubú. Éhúdù ní láti sá lọ kíákíá! Ní títi ilẹ̀kùn, ó gba inú ihò ìyẹ̀wù òrùlé sá lọ.—Onídàájọ́ 3:23, 24a.

Mímọ Ohun Tí Ó Ṣẹlẹ̀ àti Ìbìṣubú

Láìpẹ́, ará bẹ̀rẹ̀ sí í fu àwọn ìránṣẹ́ Ẹ́gílónì. Síbẹ̀, wọn kò jẹ́ wá ìbínú ọba nípa jíjáwọnú ìpàdé bòńkẹ́lẹ́ tí ó ń ṣe. Lẹ́yìn náà, wọ́n kíyè sí i pé a ti ti ilẹ̀kùn ìyẹ̀wù òrùlé pa. Wọ́n rò pé: “Ó kàn ń gbọnsẹ̀ ni nínú yàrá títutù inú lọ́hùn-ún.” Ṣùgbọ́n, bí àkókò ti ń lọ, ìdààmú rọ́pò ẹ̀mí ìfura lásán. Sùúrù àwọn ẹmẹsẹ̀ Ẹ́gílónì tán. “Látàrí èyí, wọ́n mú kọ́kọ́rọ́, wọ́n sì ṣí [àwọn ilẹ̀kùn ìyẹ̀wù òrùlé], sì wò ó! olúwa wọ́n ti ṣubú sí ilẹ̀ ní òkú!”—Onídàájọ́ 3:24b, 25, NW.

Láàárín àkókò náà, Éhúdù ti sá lọ. Ó kọjá ibi ère fínfín tí ó wà ní Gílígálì, nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ó dé Séírà, ẹkùn ilẹ̀ olókè ti Éfúráímù. Éhúdù pe gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì jọ, ó sì ṣáájú wọn nínú jíjùmọ̀ gbógun ti àwọn ará Móábù. Ìròyìn náà sọ pé, “wọ́n sì pa ìwọ̀n ẹgbàá márùn-ún ọkùnrin nínú àwọn ará Móábù ní ìgbà náà, gbogbo àwọn tí ó sígbọnlẹ̀, àti gbogbo àwọn akọni ọkùnrin; kò sí ọkùnrin kan ṣoṣo tí ó sá là.” Níwọ̀n bí a ti tẹ Móábù lórí ba, a kò yọ ilẹ̀ Ísírẹ́lì lẹ́nu mọ́ fún 80 ọdún.—Onídàájọ́ 3:26-30.

Kíkẹ́kọ̀ọ́ Láti Inú Àpẹẹrẹ Éhúdù

Ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run ni ó sún Éhúdù ṣiṣẹ́. Hébérù orí 11 kò dárúkọ rẹ̀ ní pàtó gẹ́gẹ́ bí ẹni ‘tí ó jẹ́ pé nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ ó ṣẹ́gun àwọn ìjọba nínú ìforígbárí, tí ó di akíkanjú nínú ogun, tí ó lé ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn àjòjì sá kìjokìjo.’ (Hébérù 11:33, 34) Bí ó ti wù kí ó rí, Jèhófà ti Éhúdù lẹ́yìn, bí ó ti lo ìgbàgbọ́, tí ó sì dá Ísírẹ́lì nídè kúrò lọ́wọ́ agbára ìwà ìkà agbonimọ́lẹ̀ ti Ọba Ẹ́gílónì.

Ìgboyà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ànímọ́ Éhúdù. Ó ní láti jẹ́ onígboyà láti lè lo idà lọ́nà tí ó gbéṣẹ́. Gẹ́gẹ́ bí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lóde òní, a kì í lo irú idà bẹ́ẹ̀. (Aísáyà 2:4; Mátíù 26:52) Síbẹ̀, a máa ń lo “idà ẹ̀mí,” Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Éfésù 6:17) Éhúdù jẹ́ ọ̀jáfáfá ní bí ó ṣe lo ohun ìjà rẹ̀. Àwa pẹ̀lú ní láti jẹ́ ọ̀jáfáfá nínú lílo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, bí a ti ń wàásù ìhìn rere Ìjọba náà. (Mátíù 24:14) Ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, lílọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni déédéé, fífi ìtara kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, àti gbígbáralé Bàbá wa ọ̀run nínú àdúrà, yóò ràn wá lọ́wọ́ láti fara wé àwọn ànímọ́ tí Éhúdù, ọkùnrin ìgbàgbọ́ àti ìgboyà ní tòótọ́, fi hàn.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a  Ó ṣeé ṣe kí àwọn òpó ọlọ́wọ̀ náà jẹ́ ère tí ó dúró fún nǹkan ọkùnrin. Wọ́n ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ààtò bòńkẹ́lẹ́ ti oníwà pálapàla lílékenkà.—Àwọn Ọba Kìíní 14:22-24, NW.

b  Kémóṣì ni olórí ọlọ́run àwọn ara Móábù. (Númérì 21:29; Jeremáyà 48:46) Nínú àwọn ọ̀ràn kan, ó kéré tán, ó ti ṣeé ṣe kí a ti fi àwọn ọmọdé rúbọ sí ọlọ́run èké tí ń múni ṣe họ́ọ̀ yí.—Àwọn Ọba Kejì 3:26, 27.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Éhúdù àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ gbé owó òde fún Ọba Ẹ́gílónì

[Credit Line]

A mú un jáde láti inú Illustrirte Pracht - Bibel/Heilige Schrift des Alten und Neuen Testaments, nach der deutschen Uebersetzung D. Martin Luther’s

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́