ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 3/15 ojú ìwé 29-31
  • Éhúdù Ṣẹ́ Àjàgà Aninilára

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Éhúdù Ṣẹ́ Àjàgà Aninilára
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Aláàbọ̀ Ara Ni àbí Jagunjagun?
  • “Ọ̀rọ̀ Àṣírí Kan” fún Ọba
  • Ó Sá Àsálà
  • Ẹ̀kọ́ Tí A Lè Rí Kọ́
  • Éhúdù—Ọkùnrin Ìgbàgbọ́ àti Onígboyà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìtàn Tó Ń Mórí Ẹni Wú Nípa Ọkùnrin Onígboyà Kan
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
  • Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Àwọn Onídàájọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 3/15 ojú ìwé 29-31

Éhúdù Ṣẹ́ Àjàgà Aninilára

ÌTÀN yìí jẹ́ àkọsílẹ̀ tòótọ́ kan tó sọ nípa ìgboyà àti ọgbọ́n inú. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wáyé ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọdún sẹ́yìn. Gbólóhùn tó bẹ̀rẹ̀ àkọsílẹ̀ ìtàn náà nínú Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Lẹ́ẹ̀kan sí i, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì tún bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà. Látàrí ìyẹn, Jèhófà jẹ́ kí Ẹ́gílónì ọba Móábù di alágbára ní ìdojú-ìjà-kọ Ísírẹ́lì, nítorí tí wọ́n ṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà. Síwájú sí i, ó kó àwọn ọmọ Ámónì àti Ámálékì jọ láti gbéjà kò wọn. Nígbà náà ni wọ́n lọ, wọ́n sì kọlu Ísírẹ́lì, wọ́n sì gba ìlú ńlá onígi ọ̀pẹ. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ń bá a lọ ní sísin Ẹ́gílónì ọba Móábù fún ọdún méjìdínlógún.”—Àwọn Onídàájọ́ 3:12-14.

Ilẹ̀ àwọn ọmọ Móábù wà ní ìhà ìlà oòrùn Odò Jọ́dánì àti Òkun Òkú. Àmọ́, wọ́n ti ré kọjá odò náà, wọ́n sì ti gba àgbègbè tó yí ilẹ̀ Jẹ́ríkò ká, tó jẹ́ “ìlú ńlá àwọn igi ọ̀pẹ,” nípa bẹ́ẹ̀ wọ́n jọba lé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lórí. (Diutarónómì 34:3) Ẹ́gílónì ọba Móábù, “ọkùnrin tí ó sanra gan-an,” ti fagbára gba ìṣákọ́lẹ̀ tí ń nini lára lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fún nǹkan bí ogún ọdún. (Àwọn Onídàájọ́ 3:17) Àmọ́, ìṣákọ́lẹ̀ tí aninilára yìí ń gbà lọ́wọ́ wọn ló fún wọn láǹfààní láti rẹ́yìn rẹ̀.

Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì . . . bẹ̀rẹ̀ sí ké pe Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́. Nítorí náà, Jèhófà gbé olùgbàlà kan dìde fún wọn, Éhúdù ọmọkùnrin Gérà, ọmọ ìran Bẹ́ńjámínì, ọkùnrin alòsì. Nígbà tí ó ṣe, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi owó òde ránṣẹ́ nípa ọwọ́ rẹ̀ sí Ẹ́gílónì ọba Móábù.” (Àwọn Onídàájọ́ 3:15) Jèhófà ti ní láti rí sí i pé Éhúdù ni wọ́n yàn láti lọ san ìṣákọ́lẹ̀ náà. Bíbélì kò sọ bóyá ó ti ṣe irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ rí tàbí kò ṣe é rí. Àmọ́, bí Éhúdù ṣe fara balẹ̀ múra láti pàdé ọba Ẹ́gílónì àti ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ tó lò fi hàn pé ó ṣeé ṣe kó ti mọ díẹ̀ nípa ààfin Ẹ́gílónì àti ohun tó lè bá pàdé níbẹ̀. Síbẹ̀, jíjẹ́ tó jẹ́ ọlọ́wọ́ òsì ni ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìmúra tó ṣe.

Ṣé Aláàbọ̀ Ara Ni àbí Jagunjagun?

Ohun tí ọ̀rọ̀ náà “alòsì” lédè Hébérù túmọ̀ sí ni ‘ẹni tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ kákò, tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ rọ tàbí ẹni tí wọ́n fi nǹkan de ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀.’ Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé Éhúdù jẹ́ aláàbọ̀ ara ni, bóyá tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ rọ? Ronú nípa ohun tí Bíbélì sọ nípa “ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin àṣàyàn ọkùnrin” látinú ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì. Ìwé Àwọn Onídàájọ́ 20:16 sọ pé: “Olúkúlùkù àwọn wọ̀nyí jẹ́ olùfi kànnàkànnà gbọn òkúta ba ìbú fọ́nrán irun tí kò sì ní tàsé.” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé jíjẹ́ tí wọ́n jẹ́ ọ̀jáfáfá nínú ogun jíjà wà lára ohun tó mú kí wọ́n yàn wọ́n. Àwọn ọ̀mọ̀wé kan tó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ sọ pé “alòsì” túmọ̀ sí ẹni tó lè lo ọwọ́ òsì àti ọwọ́ ọ̀tún.—Àwọn Onídàájọ́ 3:15.

Ká sòótọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn ló mọ̀ pé ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ní àwọn ọkùnrin tó ń lo ọwọ́ òsì. Ìwé 1 Kíróníkà 12:1, 2 sọ̀rọ̀ nípa àwọn kan látinú ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì tí wọ́n jẹ́ “àwọn ọkùnrin alágbára ńlá, àwọn olùrànlọ́wọ́ nínú ogun, tí wọ́n fi ọrun dìhámọ́ra, àwọn tí ń lo ọwọ́ ọ̀tún tí wọ́n sì ń lo ọwọ́ òsì láti fi ta òkúta tàbí ọfà nínú ọrun.” Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun kan ló mú kí wọ́n lè máa lo ọwọ́ méjèèjì, ohun náà ni pé “wọ́n máa ń fi nǹkan de ọwọ́ ọ̀tún àwọn ọmọ wẹ́wẹ́—nípa bẹ́ẹ̀ ‘ọwọ́ ọ̀tún wọn á wà ní dídè’—wọ́n sì máa ń kọ́ wọn láti lo ọwọ́ òsì wọn dáadáa.” Àwọn ọ̀tá Ísírẹ́lì sábà máa ń gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ láti bá jagunjagun tó jẹ́ ọlọ́wọ́ ọ̀tún jà. Látàrí èyí, ọ̀pọ̀ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí àwọn ọ̀tá ti gbà ni kò ní wúlò bí wọ́n bá pàdé àwọn jagunjagun tó jẹ́ ọlọ́wọ́ òsì.

“Ọ̀rọ̀ Àṣírí Kan” fún Ọba

Ohun tí Éhúdù kọ́kọ́ ṣe ni pé ó ṣe “idà kan fún ara rẹ̀”—idà olójú méjì kan tó kéré débi pé ó lè tọ́jú rẹ̀ sábẹ́ aṣọ rẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó ti máa wò ó pé wọ́n lè yẹ ara òun wò. Apá òsì làwọn èèyàn sábà máa ń fi idà sí, níbi tí àwọn tó jẹ́ ọlọ́wọ́ ọ̀tún ti lè tètè fà á yọ. Níwọ̀n bí Éhúdù ti jẹ́ ọlọ́wọ́ òsì, ó “sán [ohun ìjà rẹ̀] mọ́ itan rẹ̀ ọ̀tún, lábẹ́ aṣọ rẹ̀,” níbi tí kò dájú pé àwọn ẹ̀ṣọ́ ọba lè yẹ̀ wò. Nítorí náà, láìsí ìdíwọ́ èyíkéyìí, ó “gbé owó òde náà wá fún Ẹ́gílónì ọba Móábù.”—Àwọn Onídàájọ́ 3:16, 17.

Bíbélì kò sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa àwọn ohun tó kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀ ní àgbàlá Ẹ́gílónì. Ohun tí Bíbélì kàn sọ ni pé: “Ó . . . ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí [Éhúdù] ti parí gbígbé owó òde náà wá, ní kíákíá ó rán àwọn ènìyàn náà lọ, àwọn tí ó ru owó òde náà.” (Àwọn Onídàájọ́ 3:18) Éhúdù san ìṣákọ́lẹ̀ náà, ó sin àwọn tó bá a gbé ìṣákọ́lẹ̀ náà wá dé ibi tó jìnnà díẹ̀ sí ààfin ọba, ó sì padà sí ààfin lẹ́yìn tó ti ní kí wọ́n máa lọ. Kí ló fa gbogbo ohun tó ṣe wọ̀nyí? Ṣé nítorí kí wọ́n lè dáàbò bò ó làwọn ọkùnrin náà fi tẹ̀ lé e ni, àbí nítorí pé kó bàa lè gbayì ni, tàbí bóyá kó lè rí aláàárù bá a gbé ìṣákọ́lẹ̀ náà ni? Yàtọ̀ síyẹn, ṣé ó fẹ́ kí wọ́n rìn jìnnà kí nǹkan má bàa ṣe wọ́n kó tó ṣe ohun tó bá wá gan-an ni? Ohun yòówù tí Éhúdù ì báà ní lọ́kàn, ó fi ìgboyà padà sí ààfin ọba ní òun nìkan.

“[Éhúdù] yí padà ní àwọn ibi ìfọ́-òkúta tí ó wà ní Gílígálì, ó sì wí pé: ‘Mo ní ọ̀rọ̀ àṣírí kan láti bá ọ sọ, ìwọ ọba.’” Ìwé Mímọ́ kò ṣàlàyé bó ṣe ráyè dé ọ̀dọ̀ Ẹ́gílónì lẹ́ẹ̀kejì. Ṣé kò yẹ kí àwọn ẹ̀ṣọ́ ọba fura ni? Ṣé wọ́n rò pé ẹyọ ọmọ Ísírẹ́lì kan ṣoṣo kò lè ṣe ìpalára kankan fún olúwa wọn ni? Ṣé wíwá tí Éhúdù dá nìkan wá fi hàn pé ó fẹ́ fi ọ̀bẹ ẹ̀yìn jẹ àwọn ọmọ ìlú rẹ̀ níṣu ni? Ohun yòówù tí ì báà jẹ́, Éhúdù sọ pé òun fẹ́ rí ọba, wọ́n sì fún un láyè láti ṣe bẹ́ẹ̀.—Àwọn Onídàájọ́ 3:19.

Àkọsílẹ̀ tí Ọlọ́run mí sí náà ń bá a nìṣó pé: “Éhúdù sì tọ [Ẹ́gílónì] wá bí ó ti jókòó sí ìyẹ̀wù òrùlé rẹ̀ títutù tí ó jẹ́ ti òun nìkan. Éhúdù sì ń bá a lọ láti wí pé: ‘Ọ̀rọ̀ kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni mo fẹ́ bá ọ sọ.’” Kì í ṣe ọ̀rọ̀ tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni Éhúdù ń sọ o. Ohun tí Éhúdù ní lọ́kàn ni lílo idà rẹ̀. Bóyá ńṣe ni ọba yìí ń retí láti gbọ́ ọ̀rọ̀ kan látọ̀dọ̀ Kémóṣì, ọlọ́run rẹ̀, “ó dìde lórí ìtẹ́ rẹ̀.” Lẹ́yẹ-ò-sọkà, Éhúdù fa ohun ìjà rẹ̀ yọ ó sì fi gún Ẹ́gílónì níkùn. Ó ṣe kedere pé kò sí ohun tó dábùú èèkù idà náà. Nípa bẹ́ẹ̀, “èèkù rẹ̀ . . . ń wọlé tẹ̀ lé abẹ idà náà lọ tí ó fi jẹ́ pé ọ̀rá bo abẹ idà náà, . . . ìgbẹ́ sì bẹ̀rẹ̀ sí jáde wá,” bóyá láti ojú ọgbẹ́ náà tàbí látinú ìfun Ẹ́gílónì.—Àwọn Onídàájọ́ 3:20-22.

Ó Sá Àsálà

Láìṣẹ̀ṣẹ̀ máa dúró fa idà rẹ̀ yọ, “Éhúdù . . . gba ti ihò afẹ́fẹ́ jáde lọ, ṣùgbọ́n ó pa àwọn ilẹ̀kùn ìyẹ̀wù òrùlé dé nígbà tí ó jáde, ó sì tì wọ́n pa. Òun alára sì jáde lọ. Àwọn ìránṣẹ́ [Ẹ́gílónì] sì dé, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí wò, àwọn ilẹ̀kùn ìyẹ̀wù òrùlé ni ìwọ̀nyí tí a sì tì pa. Nítorí náà, wọ́n wí pé: ‘Ó kàn ń gbọnsẹ̀ ni nínú yàrá títutù inú lọ́hùn-ún.’”—Àwọn Onídàájọ́ 3:23, 24.

Kí ni “ihò afẹ́fẹ́” tí Éhúdù gbà sá lọ? Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé: “Kò sẹ́ni tó lè sọ ìtumọ̀ [ọ̀rọ̀ Hébérù náà] ní pàtó, àmọ́ àwọn kan dábàá pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ‘ìloro.’” Ṣé Éhúdù ti ilẹ̀kùn látẹ̀yìn ni, tó wá gba ọ̀nà ibòmíràn jáde? Àbí ńṣe ló fi kọ́kọ́rọ́ tó mú lára ọba tó ti kú náà ti ilẹ̀kùn láti ìta? Ṣé ńṣe ló kàn rọra rìn jáde, tó sì kọjá lára àwọn ẹ̀ṣọ́ bí ẹni pé kò sí ohunkóhun tó ṣẹlẹ̀? Ìwé Mímọ́ kò sọ fún wa. Àmọ́ o, ọ̀nà yòówù kí Éhúdù gbé e gbà, àwọn ìránṣẹ́ Ẹ́gílónì kò tètè mọ̀ pé nǹkan kan ti ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n rí ilẹ̀kùn ní títì pa. Ohun tí wọ́n rò kò ju pé ọba “kàn ń gbọnsẹ̀ ni.”

Níbi tí àwọn ìránṣẹ́ ọba ṣì ń fẹsẹ̀ palẹ̀, Éhúdù ti sá lọ. Lẹ́yìn èyí, ó pe àwọn ọmọ ìlú rẹ̀ jọ, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ tẹ̀ lé mi, nítorí tí Jèhófà ti fi àwọn ọ̀tá yín, àwọn ọmọ Móábù, lé yín lọ́wọ́.” Gbígbà tí àwọn ọkùnrin Éhúdù gba ibi pẹ́ṣẹ́pẹ́ṣẹ́ odò Jọ́dánì mọ́ àwọn ọmọ Móábù lọ́wọ́ kò jẹ́ kí àwọn ọmọ Móábù tí kò ní olórí mọ́ rí ọ̀nà gbà sá lọ sí ìlú wọn. Nípa bẹ́ẹ̀, ní “àkókò yẹn . . . [àwọn ọmọ Ísírẹ́lì] bẹ̀rẹ̀ sí ṣá Móábù balẹ̀, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ọkùnrin, tí gbogbo wọn sanra bọ̀kíbọ̀kí, gbogbo wọn sì jẹ́ akíkanjú ọkùnrin; kò sì sí ẹyọ kan tí ó sá àsálà. A sì wá tẹ Móábù lórí ba ní ọjọ́ yẹn lábẹ́ ọwọ́ Ísírẹ́lì; ilẹ̀ náà kò sì ní ìyọlẹ́nu kankan mọ́ fún ọgọ́rin ọdún.”—Àwọn Onídàájọ́ 3:25-30.

Ẹ̀kọ́ Tí A Lè Rí Kọ́

Ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé Éhúdù kọ́ wa pé kò sẹ́ni tó ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà tí kò ní ti ìka àbámọ̀ bọnu. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, Jèhófà máa ń ran àwọn tó bá fi ẹ̀mí ìrònúpìwàdà padà sọ́dọ̀ rẹ̀ lọ́wọ́.

Kì í ṣe nítorí mímọ̀-ọ́n-ṣe Éhúdù ni gbogbo ète tó pa fi kẹ́sẹ járí tàbí nítorí àìmọ̀-ọ́n-ṣe àwọn ọ̀tá. Ìsapá ẹ̀dá èèyàn kọ́ ló máa mú kí ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe kẹ́sẹ járí. Ohun náà gan-an tó mú kí Éhúdù ṣàṣeyọrí ni pé Ọlọ́run tì í lẹ́yìn láti dá àwọn èèyàn Rẹ̀ nídè, èyí sì wà níbàámu pẹ̀lú ète Ọlọ́run tí kò ṣeé dí lọ́wọ́. Ọlọ́run gbé Éhúdù dìde gẹ́gẹ́ bí onídàájọ́, “nígbà tí Jèhófà bá sì gbé àwọn onídàájọ́ dìde fún [àwọn èèyàn rẹ̀], Jèhófà a sì wà pẹ̀lú onídàájọ́ náà.”—Àwọn Onídàájọ́ 2:18; 3:15.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́