Àwọn Kókó Inú Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn
Gbogbo àwọn akéde tí iye wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́rìnlá ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dógún àti ẹ̀rìndínláàádọ́sàn-án [283,166] tó ròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn lóṣù November 2008 ṣiṣẹ́ kára gan-an lẹ́nu iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn. Wọ́n lo wákàtí tí àròpọ̀ ẹ̀ jẹ́ mílíọ̀nù mẹ́rin ó lé ọ̀kẹ́ mọ́kàndínlógún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàwá àti okòó lé nírínwó ó lé mẹ́fà [4,399,426] lóde ẹ̀rí. Iye yìí fi ọ̀kẹ́ méjìdínlógún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàáje àti ọgbọ̀nlérúgba ó lé mẹ́rin [373,234] ju ohun tá a ṣe lóṣù November ọdún 2007 lọ. Ní tòótọ́, “onítara fún iṣẹ́ àtàtà” làwọn èèyàn Jèhófà. (Títù 2:14) Gbogbo yín la rọ̀ pé kẹ́ ẹ máa bá a lọ ní síso èso púpọ̀ yanturu lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run.