Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a máa lò lóṣù April àti May: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! la máa lò. Nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tó fìfẹ́ hàn tó fi mọ́ àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi tàbí àwọn àpéjọ míì tí ètò Ọlọ́run ṣètò àmọ́ tí wọn kì í ṣe déédéé nínú ìjọ, ẹ sapá láti fún wọn ní ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ká sì ní in lọ́kàn láti fi bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú wọn. June: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Bí onílé bá ti ní ìwé yìí, ẹ fún un ní ìwé olójú ìwé 192 èyíkéyìí tá a tẹ̀ sórí bébà tó pọ́n ràkọ̀ràkọ̀ tàbí ìwé èyíkéyìí tá a tẹ̀ ṣáájú ọdún 1992.
◼ Inú wa dùn láti fi tó yín létí pé lọ́dún 2009, a máa ṣe àpéjọ àyíká àti àkànṣe lédè Faransé ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ Bàdágìrì ní July 4 àti 5 àti ní September 6. Bákan náà, a máa ṣe àpéjọ àyíká àti àkànṣe ní Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ Benin City ní May 2 àti 3 àti August 23. Èdè Faransé àti Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà la máa fi ṣe àwọn àpéjọ náà látòkèdélẹ̀. A ké sí gbogbo àwọn tó gbọ́ èdè yìí pé kí wọ́n wá.
◼ Nígbàkigbà tó o bá ń ṣètò fúnra rẹ láti rìnrìn àjò lọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn, tó o sì fẹ́ lọ sí ìpàdé ìjọ, àpéjọ àyíká tàbí àpéjọ àgbègbè níbẹ̀, ọ̀dọ̀ ẹ̀ka ọ́fíìsì tó ń bójú tó iṣẹ́ wa lórílẹ̀-èdè náà ni kó o ti béèrè déètì, àkókò àti ibi tí wọ́n á ti ṣe ìpàdé ọ̀hún. Àdírẹ́sì àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wà ní ojú ìwé tó kẹ́yìn nínú ìwé ọdọọdún wa, ìyẹn Yearbook.
◼ A fẹ́ kẹ́ ẹ fi nọ́ńbà tẹlifóònù yìí kún nọ́ńbà tẹlifóònù ẹ̀ka ọ́fíìsì tẹ́ ẹ ní lọ́wọ́, 07080662020. Ẹ tún lè pè wá sórí èyí: 07089999300; 08055502368-71. A fẹ́ kẹ́ ẹ mọ̀ pé, títí dìgbà tẹ́ ẹ máa fi gbọ́ ìsọfúnni míì, nọ́ńbà yìí ni kẹ́ ẹ máa pè wá sí 07080662020. Àkókò tá a fi ń ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì lọ́jọ́ Monday sí Friday rèé: aago méje ààbọ̀ [7:30] sí aago méjìlá ku ìṣẹ́jú mẹ́wàá [11:50] àárọ̀, lọ́sàn-án aago kan [1:00] sí aago 5:00 ìrọ̀lẹ́, lọ́jọ́ Saturday aago méje ààbọ̀ [7:30] àárọ̀ sí aago mọ́kànlá ààbọ̀ [11:30] àárọ̀. Arákùnrin tó ń gba ìpè kò ní lè ṣiṣẹ́ lórí ohun tẹ́ ẹ bá béèrè tó bá jẹ́ àkókò tá ò ṣiṣẹ́ lẹ pè wá.
◼ Ní May 29 àti 30, kò ní sáyè fún wa láti gbàlejò ní Bẹ́tẹ́lì. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ má ṣèbẹ̀wò, bẹ́ẹ̀ ni kẹ́ ẹ má ṣe wá gba ìwé láwọn ọjọ́ wọ̀nyí.