Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ May 4
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MAY 4
Orin 91
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
lv-YR orí 4 àpótí tó wà lójú ìwé 46 sí 49
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Ẹ́kísódù 23-26
No. 1: Ẹ́kísódù 24:1-18
No. 2: Kí Ni Ó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ? (lr orí 16)
No. 3: Ọmọ Ò Bá Baba Dọ́gba (td-YR 36B)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
Orin 83
5 min: Àwọn ìfilọ̀. Rán àwọn ará létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù April sílẹ̀.
5 min: “Àwọn Ìgbà Tá A Lè Lo Ìwé Àṣàrò Kúkúrú.” Fún àwọn ará níṣìírí pé kí wọ́n máa lo ìwé àṣàrò kúkúrú nígbà táyè ẹ bá yọ.
10 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
15 min: Bó Ṣe Ṣe Pàtàkì Tó Láti Fi Hàn Pé Ọ̀rọ̀ Àwọn Èèyàn Jẹ Ẹ́ Lógún. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tó dá lórí ìwé Mátíù 8:2, 3 àti Lúùkù 7:11-15. Kí nìdí táwọn èèyàn fi máa ń tẹ́tí sí wa tá a bá fi hàn pé ọ̀rọ̀ wọn jẹ wá lógún? Báwo la ṣe lè mọ ohun tí onílé wa nífẹ̀ẹ́ sí àtohun tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn? Báwo la ṣe lè fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn jẹ wá lógún nígbà tá a bá pàdé àgbàlagbà, ọmọdé, ọmọ ilé ẹ̀kọ́ gíga, òbí, ẹni tó ń ṣàìsàn tàbí ẹni tó ní ẹ̀dùn ọkàn?
Orin 223