Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ May 11
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MAY 11
Orin 117
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
lv-YR àfikún ẹ̀yìn ìwé tó wà lójú ìwé 209 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 211 ìpínrọ̀ 2
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Ẹ́kísódù 27-29
No. 1: Ẹ́kísódù 29:1-18
No. 2: Bí A Ṣe Lè Ní Ayọ̀ (lr orí 17)
No. 3: Èrò Tí Kò Tọ́ Nípa Ìdúróṣinṣin Àtàwọn Ewu Tó Rọ̀ Mọ́ Ọn
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
Orin 43
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
10 min: Ṣé O Lè Ṣe Aṣáájú-Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́ Nígbà Ọlidé? Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Kí alàgbà kan sọ̀rọ̀ lórí àwọn ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, èyí tó wà lójú ìwé 112 àti 113 nínú ìwé A Ṣètò Wa. Kó sọ àwọn ohun tó yẹ káwọn tó máa ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ dójú ìlà rẹ̀. Ní káwọn tó ti ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ sọ àwọn ìbùkún tí wọ́n gbádùn.
10 min: Ẹ̀yin Ìdílé, Ẹ Máa Múra Iṣẹ́ Ìwàásù Pa Pọ̀! Ní ṣókí, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu olórí ìdílé méjì tó máa ń lo àkókò díẹ̀ nígbà Ìjọsìn Ìdílé wọn láti múra sílẹ̀ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́. Báwo ni wọ́n ṣe ń ṣe é, àǹfààní wo ló sì ti ṣe fún wọn? Ṣàṣefihàn bí olórí ìdílé kan ṣe fi bó ṣe máa lo ìwé ìròyìn lóde ẹ̀rí dánra wò lákòókò Ìjọsìn Ìdílé.
10 min: “Kọ́ni Lọ́nà Tó Rọrùn.” Ìbéèrè àti ìdáhùn.
Orin 158