ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 11/13 ojú ìwé 3
  • Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ń Sa Agbára

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ń Sa Agbára
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àkànṣe ti Ọdún 2010
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
  • ‘Oúnjẹ Ní Àkókò Tí Ó Bẹ́tọ̀ọ́ Mu’
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Tuntun fún Àpéjọ Àkànṣe
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Tuntun fún Àpéjọ Àkànṣe
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
km 11/13 ojú ìwé 3

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ń Sa Agbára

1. Kí ni ẹṣin ọ̀rọ̀ àpéjọ àkànṣe ti ọdún 2014?

1 Bíbélì yàtọ̀ pátápátá sí àwọn nǹkan tí àwọn èèyàn aláìpé ṣe. Ó lágbára láti yí àwa èèyàn pa dà, ó máa ń mú kí èrò àti ìwà wa bá ohun tí Jèhófà fẹ́ mu. Báwo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tiẹ̀ ṣe lágbára tó? Báwo la ṣe lè jàǹfààní agbára tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ ní ìgbésí ayé wa? Báwo la ṣe lè túbọ̀ já fáfá nínú bá a ṣe ń fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ran àwọn èèyàn lọ́wọ́? Ó dá wa lójú pé ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí máa jẹ́ kí ìgbàgbọ́ yín lágbára sí i torí pé a máa jíròrò wọn nínú àpéjọ àkànṣe wa ti ọdún iṣẹ́ ìsìn 2014. Ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ń Sa Agbára,” a gbé e ka Hébérù 4:12.

2. Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká fetí sí ìdáhùn wọn?

2 Wá Ìdáhùn Sáwọn Ìbéèrè Yìí: Bí o ṣe ń tẹ́tí sí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, kọ ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e yìí sílẹ̀.

• Kí nìdí tí kò fi yẹ ká ṣiyè méjì nípa Ọ̀rọ̀ Jèhófà? (Sm. 29:4)

• Báwo ni agbára tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní ṣe lè nípa lórí ìgbésí ayé wa? (Sm. 34:8)

• Báwo lo ṣe lè jẹ́ kí àwọn èèyàn rí agbára tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ? (2 Tím. 3:16, 17)

• Kí la lè ṣe kí ayé Sátánì má bàa fi ẹ̀tàn mú wa? (1 Jòh. 5:19)

• Báwo ni ẹ̀yin ọ̀dọ́ ṣe lè ṣe àṣeyọrí nípa tẹ̀mí? (Jer. 17:7)

• Báwo la ṣe lè jẹ́ alágbára, kódà nígbà tá a jẹ́ aláìlera? (2 Kọ́r. 12:10)

• Kí ló máa jẹ́ ká lè túbọ̀ máa ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ ní ìgbésí ayé wa, títí kan yíyí àwọn àṣà àti ìwà tó ti wọni lẹ́wù pa dà? (Éfé. 4:23)

3. Yàtọ̀ sí pé ká fetí sílẹ̀ nígbà tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ bá ń lọ lọ́wọ́, àwọn ọ̀nà wo la tún lè gbà jàǹfààní látinú àpéjọ àkànṣe náà?

3 Ó dájú pé a máa jàǹfààní gan-an látinú àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì tá a máa gbọ́ ní àpéjọ náà! Bákan náà, bíi ti àpéjọ àyíká àti àpéjọ àgbègbè, àpéjọ àkànṣe yìí máa fún wa láǹfààní láti mú kí ìfẹ́ wa gbòòrò síwájú, ká sì ní ìfararora pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin tó wá láti àwọn ìjọ míì. (Sm. 133:1-3; 2 Kọ́r. 6:11-13) Nítorí náà wá àyè láti bá àwọn ọ̀rẹ́ rẹ sọ̀rọ̀ kí o sì tún yan àwọn ọ̀rẹ́ tuntun. Tí a bá yan alábòójútó àgbègbè tàbí arákùnrin kan láti Bẹ́tẹ́lì láti jẹ́ olùbánisọ̀rọ̀ tí a rán wá sí àpéjọ àkànṣe yín, o ò ṣe wá bó o ṣe máa kí òun àti ìyàwó rẹ̀? Láìsí àní-àní, a ní ìdí tó pọ̀ láti máa fojú sọ́nà fún àpéjọ àkànṣe wa tó ń bọ̀!

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́