Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Tuntun fún Àpéjọ Àkànṣe
A bẹ̀rẹ̀ àpéjọ àkànṣe ní ọdún 1987. Ìkórajọ ọlọ́jọ́ kan yìí ń gbé àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ró, ó sì ń gbé àwọn olùfìfẹ́hàn tí ń pésẹ̀ ró pẹ̀lú. Bẹ̀rẹ̀ ní February 1999, ìtòlẹ́sẹẹsẹ tuntun fún àpéjọ àkànṣe ni a óò lò. Ìwọ yóò rí i pé ọ̀rọ̀ àsọyé mẹ́sàn-án àti ọ̀pọ̀ ìfọ̀rọ̀wáni-lẹ́nuwò òun ìrírí ṣàǹfààní nípa tẹ̀mí.
“Máa Fi Ìmọrírì Hàn fún Tábìlì Jèhófà” ni ẹṣin ọ̀rọ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ tuntun náà. (Aísá. 65:14; 1 Kọ́r. 10:21) Yóò fún ìpinnu wa lókun pé ìjọsìn Jèhófà ni ó gbọ́dọ̀ gba ipò iwájú nínú ìgbésí ayé wa. (Sm. 27:4) Apá tí ó jẹ́ ti alábòójútó àyíká tí a pe àkòrí rẹ̀ ní “Ṣíṣàyẹ̀wò Àwọn Ìtẹ̀sí Ọkàn-Àyà Wa” yóò ní í ṣe pẹ̀lú ìṣarasíhùwà wa ní ti lílọ sí ìpàdé. Olùbánisọ̀rọ̀ tí a óò gbà lálejò yóò fi hàn wá bí a ṣe lè “Di Ipò Tẹ̀mí [Wa] Mú Nípa Jíjẹun ní Orí Tábìlì Jèhófà.” A óò tún fún àwọn ọ̀dọ́ tí ó wà nínú ètò Jèhófà ní ìṣírí gbígbéṣẹ́ láti máa dúró ṣinṣin nínú sísin Ọlọ́run. Lájorí àwíyé olùbánisọ̀rọ̀ tí ń ṣèbẹ̀wò tí a pe àkòrí rẹ̀ ní, “A Fún Wa Lókun Nípa Tẹ̀mí Láti Fi Ìgbóyà Jẹ́rìí,” yóò fi bí àwọn ìpèsè tí a ń ṣe nípasẹ̀ ìjọ ṣe ń mú wa gbára dì láti fi ìgbóyà jẹ́rìí nípa Ìjọba náà hàn. Ta ni kì yóò fẹ́ jàǹfààní láti inú ìtòlẹ́sẹẹsẹ yìí?
Kí àwọn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèyàsímímọ́ tí wọ́n fẹ́ ṣe batisí fi tó alábòójútó olùṣalága létí bí ó bá ti ṣeé ṣe kí ó yá tó. Ó dá wa lójú pé bí a ṣe bẹ̀rẹ̀ ọdún kejìlá nínú ètò àpéjọ àkànṣe, gbogbo àwọn tí ó bá pésẹ̀ ni a óò túbọ̀ mú sunwọ̀n sí i nípa tẹ̀mí fún iṣẹ́ tí ń bẹ níwájú.