Fífi Ìwé Pẹlẹbẹ Béèrè Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́
1 Àwọn ìròyìn tí a ń rí gbà káàkiri ayé fi hàn pé ìwé pẹlẹbẹ Kí Ni Ọlọ́run Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? jẹ́ ohun èlò tí ó bùáyà tí a lè lò láti fi kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni a ń fi ìwé pẹlẹbẹ yìí bẹ̀rẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. O ha ti ṣàṣeyọrí ní fífi ìwé pẹlẹbẹ Béèrè bẹ̀rẹ̀ sí báni ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bí?
2 Nígbà tí ó jẹ́ pé ó rọrùn fún ọ̀pọ̀ jù lọ láti fi ìwé pẹlẹbẹ yìí sóde, ó nira fún àwọn kan láti mọ ohun tí wọn yóò sọ kí wọ́n bàa lè bẹ̀rẹ̀ sí báni ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́. Àwọn ọ̀nà wo ni àwọn mìíràn ti rí pé ó gbéṣẹ́ láti bẹ̀rẹ̀ sí fi ìwé pẹlẹbẹ Béèrè báni ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Ó yẹ kí àwọn àbá tí ó tẹ̀ lé e wọ̀nyí ṣèrànwọ́.
3 Sọ Pé O Fẹ́ Ṣàlàyé Bí A Ṣe Ń Ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́: Dípò kí a kàn fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ onílé nígbà tí a bá ń ṣe ìkésíni tàbí ìpadàbẹ̀wò àkọ́kọ́, a lè ṣàlàyé bí a óò ṣe darí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà fún wọn. Èyí sábà máa ń mú ìrújú tí àwọn onílé lè ní nípa ọ̀rọ̀ náà “ìkẹ́kọ̀ọ́” àti àníyàn tí wọ́n lè máa ṣe kúrò. Nígbà tí a bá ti mọ bí a ṣe lè ṣàlàyé rẹ̀ fún wọ́n, a óò rí i pé wẹ́rẹ́ ni a óò bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ní lílo ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tí ó rọrùn.
4 Ìmúrasílẹ̀ Ni Oògùn Rẹ̀: Bí a bá ṣe múra sílẹ̀ dáadáa tó ni yóò ṣe yá wa lára tó láti bẹ̀rẹ̀ sí báni ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ìmúrasílẹ̀ yóò ràn wá lọ́wọ́ láti borí ohun tí ó lè mú kí a máa lọ́ tìkọ̀ láti ní ìpín nínú bíbáni ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí a bá fi ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ wa dánra wò lọ́pọ̀ ìgbà, a óò túbọ̀ lè bá onílé jíròrò lọ́nà tí ó já gaara, a óò lè ṣàlàyé lọ́nà tí ó yọ̀ mọ́ wa lẹ́nu tí a óò sì gbé e kalẹ̀ lọ́nà tiwa fúnra wa. Yàtọ̀ sí pé èyí yóò jẹ́ kí ọ̀kan wa balẹ̀, yóò tún jẹ́ kí ara tu onílé pẹ̀lú.
5 Nígbà tí o bá ń ṣe ìfidánrawò rẹ̀, ó dára kí o wo aago láti mọ bí àkókò náà ṣe gùn tó kí o bàa lè sọ àkókò tí yóò gbà láti ṣàlàyé bí a ṣe ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà fún onílé. Lẹ́yìn tí arákùnrin kan sọ ẹni tí òun jẹ́, ó wá sọ pé: “Ńṣe ni mo kàn yà síbí láti fi bí ìtòlẹ́sẹẹsẹ bí a ṣe ń báni ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ilé lọ́fẹ̀ẹ́ ṣe rí hàn ọ́. Nǹkan bí ìṣẹ́jú márùn-ún ni yóò gbà láti fi hàn ọ́. Ṣé o lè yọ̀ǹda ìṣẹ́jú márùn-ún?” A lè lo nǹkan bí ìṣẹ́jú márùn-ún láti ṣàlàyé bí Ẹ̀kọ́ Kìíní nínú ìwé Béèrè ṣe lọ fún un. Àmọ́ ṣá o, kìkì ẹsẹ Ìwé Mímọ́ díẹ̀ ni a óò lè yàn láti kà láàárín ìwọ̀nba àkókò yìí, ṣùgbọ́n bí a bá fi ìṣẹ́jú mélòó kan parí ẹ̀kọ́ kìíní, yóò lè ṣeé ṣe fún onílé láti mọ bí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ṣe máa ń rí fún ìgbà àkọ́kọ́. Lẹ́yìn náà, jẹ́ kí ó mọ̀ pé nígbà tí o bá padà wá láti bá a ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Ẹ̀kọ́ Kejì, ìwọ̀nba ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ni yóò gbà.
6 Àwọn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tí ó tẹ̀ lé e yìí jẹ́ èyí tí ó gbéṣẹ́:
◼ “Èmi yóò fẹ́ láti fi hàn ọ́ bí a ṣe ń lo ìwé pẹlẹbẹ yìí, Kí Ni Ọlọ́run Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?, láti fi báni ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ilé lọ́nà tí ó rọrùn tí ó sì yá kíákíá. Ọ̀pọ̀ ènìyàn ti rí i pé bí àwọn ṣe ń lo ìwọ̀nba ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún péré lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ fún ọ̀sẹ̀ mẹ́rìndínlógún, ó ṣeé ṣe fún àwọn láti rí àwọn ìdáhùn títẹ́rùn tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu sí àwọn ìbéèrè pàtàkì wọ̀nyí nípa Bíbélì.” Fi ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn kókó ẹ̀kọ́ inú ìwé náà hàn án ní ṣókí. Bí o ṣe ń ṣí i sí Ẹ̀kọ́ Kìíní, sọ pé: “Bí o bá lè yọ̀ǹda nǹkan bí ìṣẹ́jú márùn-ún, a óò ṣàlàyé bí èyí ṣe máa ń rí fún ọ. Àkòrí Ẹ̀kọ́ Kìíní ni ‘Bí O Ṣe Lè Mọ Ohun Tí Ọlọrun Ń Béèrè.’” Lẹ́yìn náà, ka ìbéèrè mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, kí o sì ṣàlàyé nípa àwọn nọ́ńbà tí ó wà nínú àkámọ́. Ka ìpínrọ̀ kìíní, kí o sì fi bí onílé yóò ṣe wá ìdáhùn kàn hàn án. O lè sọ pé kí onílé ka ìpínrọ̀ kejì. Kí o wá sọ pé: “Láti inú ohun tí o kà yìí, báwo ni ìwọ yóò ṣe dáhùn ìbéèrè yìí? [Tún ìbéèrè náà kà, kí o sì jẹ́ kí onílé ṣàlàyé.] Ìwọ yóò ṣàkíyèsí pé a so àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan pọ̀ mọ́ ìpínrọ̀ kọ̀ọ̀kan. Ìwọ̀nyí ni ó jẹ́ kí a rí bí Bíbélì ṣe dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí. Bí àpẹẹrẹ, jẹ́ kí a ka 2 Tímótì 3:16, 17, kí a wò ó bóyá ó ti ìdáhùn rẹ nípa ẹni tí ó jẹ́ òǹṣèwé Bíbélì lẹ́yìn.” Lẹ́yìn tí ó bá ti ka ìpínrọ̀ kẹta, tí ẹ ti yẹ ìbéèrè wò, tí ẹ sì ti ka Jòhánù 17:3, pe àfiyèsí onílé sí ìmọ̀ tí ó ti rí gbà nípa ṣíṣàtúnyẹ̀wò Ẹ̀kọ́ Kìíní. Níhìn-ín, o lè wá ṣí i sí Ẹ̀kọ́ Kejì kí o sì ka ìbéèrè tí ó kẹ́yìn, “Àwọn ọ̀nà méjì wo ni a lè gbà kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọrun?” Lẹ́yìn náà, béèrè pé: “Ìgbà wo ni ó máa lè yọ̀ǹda nǹkan bí ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún kí a fi lè kọ́ Ẹ̀kọ́ Kejì kí a sì dáhùn ìbéèrè yẹn?”
7 Ó ṣe pàtàkì pé kí a mú kí ìjíròrò náà rọrùn kí a sì yin onílé nígbà tí ó bá ṣeé ṣe. Nígbà tí o bá ń ṣètò ìgbà tí o máa tún padà wá, dípò tí ìwọ yóò fi béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé ṣe yóò fẹ́ kí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà máa bá a lọ, wulẹ̀ fún un níṣìírí pé kí ó ṣe ohun kan náà tí ẹ ń ṣe nínú ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀ lé e. Jẹ́ kí ó mọ̀ pé o fẹ́ láti tún padà wá. O tún lè fún àkẹ́kọ̀ọ́ náà níṣìírí pé kí ó fi ìwé pẹlẹbẹ náà sí ibi tí ó dára tí ó sì wà lárọ̀ọ́wọ́tó tí yóò fi lè tètè mú un jáde nígbà tí o bá tún padà wá.
8 Ṣe Ìpinnu: Nígbà tí ó jẹ́ pé ìmúrasílẹ̀ ni yóò jẹ́ kí a ṣàṣeyọrí, a ní láti pinnu láti máa ṣe bẹ́ẹ̀ nìṣó. Ó lè jẹ́ ìpèníjà láti lè fi ìṣẹ́jú mélòó kan kọ́ni ní ẹ̀kọ́ kan, nítorí náà, pinnu láti fi ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ dánra wò lọ́pọ̀ ìgbà bí ó bá ṣe yẹ sí, kí ọ̀rọ̀ bàa lè yọ̀ mọ́ ọ lẹ́nu nígbà tí o bá ń ṣàlàyé bí a ṣe ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Gbìyànjú láti fi bí a ṣe ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ han gbogbo ẹni tí o bá bá pàdé lẹ́nu ọ̀nà tàbí lọ́nà tí kò jẹ́ bí àṣà. Bí ó bá ṣòro fún ọ láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, má ṣe rẹ̀wẹ̀sì. Ìpinnu àti ìfẹ́ àtinúwá láti fi òtítọ́ kọ́ ẹlòmíràn ni ó ń béèrè láti lè ṣàṣeyọrí láti bẹ̀rẹ̀ sí báni ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.—Gál. 6:9.
9 Nípa fífi àwọn àbá wọ̀nyí sílò, ìwọ náà lè ní àǹfààní láti ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ sí rìn ní ọ̀nà ìyè, nípa fífi ìwé pẹlẹbẹ Béèrè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kí o sì máa fi darí rẹ̀ nìṣó.—Mát. 7:14.