Ṣé Ò Ń Lo Ìwé Pẹlẹbẹ Béèrè Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
1 Ǹjẹ́ o mọ̀ pé tó o bá ń bá ẹnì kan jíròrò nípa Bíbélì déédéé, tí o sì ń lo ọ̀kan lára àwọn ìwé tá a dámọ̀ràn, kódà bí àkókò tí ò ń lò kò bá tiẹ̀ gùn, ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lò ń darí yẹn? Dájúdájú, bó ṣe rí nìyẹn, bó tiẹ̀ jẹ́ ẹnu ọ̀nà lẹ̀ ń dúró sí ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà tàbí lórí tẹlifóònù. O ò ṣe ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe ní oṣù May àti June láti bẹ̀rẹ̀ irú ìkẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ nípa lílo ìwé pẹlẹbẹ Béèrè?
2 Múra Sílẹ̀ Kó O Bàa Lè Ṣàṣeyọrí: Nígbà tó o bá ń fi ìwé pẹlẹbẹ Béèrè lọni, jẹ́ kí ohun tó o fẹ́ jíròrò ṣe kedere lọ́kàn rẹ. Tó bá jẹ́ pé ìpadàbẹ̀wò lo fẹ́ lọ ṣe, ronú nípa ohun tẹ́ ẹ kọ́kọ́ jọ sọ̀rọ̀ lé lórí. Béèrè lọ́wọ́ ara rẹ pé: ‘Èwo nínú àwọn ìpínrọ̀ inú ìwé pẹlẹbẹ náà ni mo lè pe àfiyèsí sí láti fi máa bá ọ̀rọ̀ wa lọ tá á sì yọrí sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?’ Bó bá jẹ́ pé ńṣe lò ń lọ láti ilé dé ilé, ronú lórí irú kókó ọ̀rọ̀ tó lè fa ọ̀dọ́langba, àgbàlagbà, ọkùnrin tàbí obìnrin mọ́ra. Wo àwọn àkòrí inú ìwé pẹlẹbẹ náà, kó o sì mú kókó ẹ̀kọ́ kan tó máa fani mọ́ra. Lẹ́yìn tó o bá ti pinnu irú ọ̀nà ìyọsíni tí wàá lò, fi dánra wò fún bí ìgbà mélòó kan. Ọ̀nà kan tó o lè gbà ṣàṣeyọrí lèyí jẹ́.
3 A gbé “Àwọn Àbá fún Fífi Ìwé Pẹlẹbẹ Béèrè Lọni” jáde nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù January 2002. Mẹ́jọ làwọn àbá náà. Nígbà tí àpótí náà, “Fífi Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lọni Ní Tààràtà” sì fi hàn bí a ṣe lè lo ìwé pẹlẹbẹ náà láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́. O lè sọ àbá àkọ́kọ́ lọ́nà yìí:
◼ “Ǹjẹ́ o mọ̀ pé láàárín ìṣẹ́jú díẹ̀ péré, o lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè pàtàkì kan nínú Bíbélì? Fún àpẹẹrẹ, kí ló dé tí àwọn ìsìn tó pe ara wọn ní Kristẹni fi pọ̀ rẹpẹtẹ? Ǹjẹ́ o tiẹ̀ ti ronú nípa kókó yẹn rí?” Lẹ́yìn tí ẹni yẹn bá ti dáhùn, ṣí ìwé pẹlẹbẹ náà sí ẹ̀kọ́ 13 kó o sì bá a jíròrò ìpínrọ̀ kìíní àti ìkejì. Tí àyè bá wà, ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tàbí méjì kí o sì jíròrò rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀. Lẹ́yìn náà ka ìbéèrè tó gbẹ̀yìn lókè ojú ewé náà, kí o sì sọ pé: “Ìyókù ẹ̀kọ́ náà sọ àmì márùn-ún tá a lè fi dá ìsìn tòótọ́ mọ̀ yàtọ̀. Inú mi á dùn láti padà wá kí n sì wá jíròrò wọn pẹ̀lú rẹ.”
4 Má Ṣe Jáwọ́: Lo gbogbo àǹfààní tó o bá ní láti fi ìwé pẹlẹbẹ Béèrè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bẹ̀bẹ̀ fún ìbùkún Jèhófà. (Mát. 21:22) Tó ò bá jáwọ́ nínú akitiyan rẹ, o lè ní ayọ̀ ríran ẹnì kan lọ́wọ́ láti tẹ́wọ́ gba ìhìn rere náà!