Fara Wé Jèhófà Nípa Fífi Tinútinú Ṣàníyàn Nípa Àwọn Ẹlòmíràn
1 Jèhófà ni àpẹẹrẹ títóbi lọ́lá jù lọ ti ẹni tí ó fi tinútinú ṣàníyàn nípa àwọn ẹlòmíràn. Gẹ́gẹ́ bí Ọba Aláṣẹ Àgbáyé, ó fi taratara mọ àìní àwọn ẹ̀dá rẹ̀. (1 Pet. 5:7) Jésù rọ àwọn ọmọ ẹ̀yin rẹ̀ láti gbé ànímọ́ Bàbá rẹ̀ yọ, ẹni tí ó mú kí oòrùn là, kí òjó sì rọ̀ sórí àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo. (Mat. 5:45) O lè fara wé Jèhófà nípa fífi tinútinú ṣàníyàn nípa àwọn ẹlòmíràn—ní ṣíṣe tán láti ṣàjọpín ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà pẹ̀lú gbogbo ẹni tí o bá pàdé. Nípa mímọ àwọn ohun tí ń bẹ nínú àwọn ìwé pẹlẹbẹ tí a óò lò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní July dáradára, ìwọ yóò wà ní ipò dídára láti pèsè ìrànlọ́wọ́ tẹ̀mí fún àwọn ẹlòmíràn. Àwọn àbá tí ó tẹ̀ lé e wọ̀nyí pèsè ìmọ̀ràn lóri bí o ṣe lè múra sílẹ̀ fún ìkésíni àkọ́kọ́, kí o sì ṣiṣẹ́ lórí ọkàn-ìfẹ́ tí a fi hàn nípa ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò tí ó bọ́ sí àkókò.
2 Nígbà tí o bá ń fi ìwé pẹlẹbẹ náà, “Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?” lọni, o lè sọ pé:
◼ “O ha ti ṣe kàyéfì rí nípa ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba àwọn ènìyàn láti máa jìyà, bí ó bá bìkítà nípa wọn ní ti gidi? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Kì í ṣe kìkì pé ìwé pẹlẹbẹ yìí pèsè ìdáhùn tí ó tẹni lọ́rùn sí ìbéèrè yìí nìkan ni, ṣùgbọ́n ó tún fi hàn pé Ọlọ́run tí ṣèlérí láti ṣàtúnṣe gbogbo ìbàjẹ́ tí ènìyán tí mú wá sórí ara rẹ̀ àti wá bá ibùgbé rẹ̀ orí ilẹ́ ayé.” Ka ìpínrọ̀ 23 ní ojú ìwé 27. Fi àwòrán tí ó wà ní ìsàlẹ̀ rẹ̀ hàn, kí o sì ka Sáàmù 145:16 láti inú ìpínrọ̀ 22. Fi ìwé náà lọ̀ ọ́ ní iye tí a fi ń lọni. Bí ó bá gbà á, béèrè ìbéèrè kan tí ìwọ yóò dáhùn nígbà ìbẹ̀wò rẹ tí ó tẹ̀ lé e, irú bí: “Ìwọ yóò ha fẹ́ mọ bí Ọlọ́run yóò ṣe ṣàṣeparí ète rẹ̀ ti mímú ìbùkún wá fún aráyé àti ti sísọ ilẹ̀ ayé di párádísè kan?”
3 Nígbà tí o bá ń ṣèpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tí o fún ní ìwé pẹlẹbẹ náà, “Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?”, o lè bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò míràn ní ọ̀nà yìí:
◼ “Nígbà tí mo kàn sí ọ kẹ́yìn, a jíròrò pé Ọlọ́run bìkítà nípa wa ní tòótọ́, pé ó sì jẹ́ ète rẹ̀ láti ṣàtúnṣe gbogbo ìbàjẹ́ tí ènìyán ti mú wá sórí ara rẹ̀ àti wá bá ibùgbé rẹ orí ilẹ́ ayé.” Ṣí ìwé pẹlẹbẹ náà sí àwòrán tí ó wà ní ojú ìwé 2 àti 3, kí o sì sọ pé: “A mú ìjíròro wa wá sí ìparí pẹ̀lú ìbéèrè náà, Báwo ni Ọlọ́run yóò ṣe ṣàṣeparí ète rẹ̀ ti mímú ìbùkún wá fún aráyé àti sísọ ilẹ̀ ayé di párádísè kan? Kí ni èrò rẹ?” Jẹ́ kí ó fèsì. Ṣí i sí ojú ìwé 17, kí o sì ka ìpínrọ̀ 2 àti Dáníẹ́lì 2:44. Lẹ́yìn náà, ka ìpínrọ̀ 12 ní ojú ìwé 18. Béèrè lọ́wọ́ onílé bí yóò bá fẹ́ yẹ apá 9 ìwé pẹlẹbẹ náà wò pẹ̀lú rẹ. Bí ó bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ pẹ̀lu rẹ̀.
4 Ìyọsíni kan tí o lè lò ní fífi ìwé pẹlẹbẹ náà, “Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú” lọni nìyí. Fi èpo iwájú rẹ̀ hàn, kí o sì wí pé:
◼ “Lónìí, a ń pín ìwé pẹlẹbẹ yìí, tí ó ti mú ìtùnú àti ìrètí wá fún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn tí ó ti pàdánù àwọn àyànfẹ́ wọn nínú ikú. O ha ti ṣe kàyéfì rí nípa ìrètí tí ó wà fún àwọn òkú? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Bíbélì sọ ní kedere nípa ìlérí Ọlọ́run nípa àjíǹde.” Ka Jòhánù 5:28, 29. Ṣí ìwé pẹlẹbẹ náà, kí o sì sọ̀rọ̀ lórí àwọn kókó tí ó wà nínú ìpínrọ̀ tí ó kẹ́yìn ní ojú ìwé 28 àti ní ìpínrọ̀ àkọ́kọ́ ní ojú ìwé 31. Fi àwọn àwòrán tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn hàn. Fi ìwé pẹlẹbẹ náà lọ̀ ọ́. O lè ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ìpadàbẹ̀wò nípa bíbéèrè pé, “Báwo ni ó ṣe lè dá wa lójú pé a óò mú ikú kúrò pátápátá nígbẹ̀yìngbẹ́yín?”
5 Níbi tí o ti fi ìwé pẹlẹbẹ náà, “Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú” síta, o lè fẹ́ láti lo ìgbékalẹ̀ yìí nígbà ìpadàbẹ̀wò:
◼ “Nígbà tí a sọ̀rọ̀ kẹ́yìn, a jíròrò nípa ìrètí àgbàyanu àjíǹde. Ìwé pẹlẹbẹ tí mo fi sílẹ̀ fún ọ ṣàlàyé ìdí tí ó fi lè dá wa lójú pé a óò mú ikú kúrò pátápátá nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Àwọn ìlérí Ọlọ́run kò ha tù ọ́ nínú, kí ó sì fi ọ́ lọ́kàn balẹ̀ bí?” Jẹ́ kí ó fèsì. Lẹ́yìn náà, ṣí ìwé pẹlẹbẹ náà sí ojú ìwé 31, kí o sì ka ìpínrọ̀ kejì àtì kẹta, àti Ìṣípayá 21:1-4. Tẹnu mọ́ ìrètí tí a ní, ti gbígbádùn ìwàláàyè láìní kú mọ́. Ní sísinmi lórí ìfẹ́ tí a fi hàn, àti lórí ipò àyíká lọ́ọ́lọ́ọ́, o lè fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ̀ ọ́ nínú ìwé Ìmọ̀ tàbí kí o béèrè ìbéèrè míràn, láti ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ìpadàbẹ̀wò tí ó tẹ̀ lé e.
6 O lè sọ ohun tí ó tẹ̀ lé e yìí nígbà tí o bá ń fi ìwé pẹlẹbẹ náà, “Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?” lọni:
◼ “Ọ̀pọ̀ ènìyán ti ṣe kàyéfì nípa ohun tí ète ìgbésí ayé jẹ́. Wọ́n ti bí ara wọn léèrè pé: ‘Èé ṣe tí mo fi wà níhìn-ín? Níbo ni mò ń lọ? Kí ni ọjọ́ ọ̀lá ní nípamọ́ fún mi?’ Níbo ni o rò pé a ti lè rí ìdáhùn? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Kíyè sí ohun tí Bíbélì sọ. [Ka Sáàmù 36:9.] Kò ha bọ́gbọ́n mu láti dórí ìpinnu pé Ẹlẹ́dàá ènìyàn ni ó wà ní ipò tí ó dára jù lọ láti ṣàlàyé ìdí tí a fi wà níhìn-ín? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ìwé pẹlẹbẹ yìí fi ète gíga lọ́lá tí Ọlọ́run ní nípamọ́ fún wa hàn.” Ṣí i sí ojú ìwe 20 àti 21, ka àkọlé àwòrán, kí o sì ṣàlàyé àwòrán náà; lẹ́yìn náà, fi ìwé pẹlẹbẹ náà lọ̀ ọ́ ní iye tí a fi ń lọni. Bí ó bá gbà á, béèrè pé: “Báwo ni ó ṣe lè dá wa lójú pé ó ṣì jẹ́ ète Ọlọ́run fún ẹ̀dá ènìyàn láti gbé títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé?”
7 Bí o bá fi ìwé pẹlẹbẹ náà, “Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?” síta, o lè sọ ohun kan bí èyí, nígbà tí o bá padà lọ:
◼ “Nígbà ìbẹ̀wò mi tí ó kẹ́yìn, mo pilẹ̀ gbádùn jíjíròro ojú ìwòye Bíbélì pé ìgbésí ayé ènìyàn ní ète nínú ní ti gidi, pẹ̀lú rẹ.” Fi àwòrán tí ó wà ní ojú ìwé 31 hàn án, kí o sì béèrè pé, “Báwo ni ó ṣe lè dá wa lójú pé ó ṣì jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run pé kí ènìyàn gbé títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé?” Ka ìpínrọ̀ 3 ní ojú ìwe 20. Jíròrò àwọn kókó tí ó wà lábẹ́ ìsọ̀rí orí ọ̀rọ̀ náà, “Ó Ṣì Jẹ Ète Ọlọrun,” ní ojú ìwé 21. Yíjú sí ẹ̀yìn ìwé pẹlẹbẹ náà, kí o sì kà nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́ tí a ṣèfilọ̀ rẹ̀. Fi ìwé Ìmọ̀ hàn án, kí o sì yọ̀ǹda láti fi bí a ti ń lò ó gẹ́gẹ́ bí àrànṣe fún kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì hàn án.
8 Iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa yẹ kí ó fi ìdàníyàn àtọkànwá tí a ní nínú ríran àwọn aláìlábòsí ọkàn lọ́wọ́ láti “wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́,” hàn. (1 Tim. 2:4) Nítorí náà, wá àyè nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ iṣẹ́ ìsìn rẹ láti padà lọ sọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn tí o bá fún ní ìwé pẹlẹbẹ. Fífi tí o ń fi àníyàn àtọkànwá hàn fún wọn lè yọrí sí ríran àwọn tí ń kẹ́dùn, tí wọ́n sì ń kígbe nítorí ohun ìríra tí wọ́n ń ṣe nínú àwọn ìsìn èké lọ́wọ́ láti di ẹni tí a sàmì sí fún lílà á já. (Isk. 9:4, 6) Ìwọ yóò tún ní ìdùnnú àti ìtẹ́lọ́rùn tí ń wá láti inú mímọ̀ pé ò ń fara wé Jèhófà nípa fífi tinútinú ṣàníyàn nípa àwọn ẹlòmíràn.—Fi wé Fílípì 2:20.