ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 8/96 ojú ìwé 8
  • Fi Àwọn Ìwé Pẹlẹbẹ Pòkìkí Ìhìn Rere Ìjọba Náà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Fi Àwọn Ìwé Pẹlẹbẹ Pòkìkí Ìhìn Rere Ìjọba Náà
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Fara Wé Jèhófà Nípa Fífi Tinútinú Ṣàníyàn Nípa Àwọn Ẹlòmíràn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Bá A Ṣe Lè Lo Ìwé Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
  • A Máa Lo Ìwé Pẹlẹbẹ Tuntun Lóde Ẹ̀rí!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
  • Ǹjẹ́ O Máa Ń Lo Àwọn Ìwé Pẹlẹbẹ Yìí?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
km 8/96 ojú ìwé 8

Fi Àwọn Ìwé Pẹlẹbẹ Pòkìkí Ìhìn Rere Ìjọba Náà

1 Ẹ wo bí o ti dùn mọ́ni nínú tó láti mọ òtítọ́ àti láti wà lára àwọn tí ń fi tìtaratìtara pòkìkí ìhìn rere! Ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn ènìyàn tí ó wà lóde ètò àjọ Ọlọ́run gbọ́ ìhìn rere Ìjọba náà. A ṣàlàyé òtítọ́ Ìjọba náà lọ́nà tí ó rọrùn nínú àwọn ìwé pẹlẹbẹ náà, Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!, “Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun,” àti Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá. Wọ́n ṣàgbéyọ ìgbésí ayé lórí ilẹ̀ ayé lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run lọ́nà ṣíṣe kedere, wọ́n sì darí òǹkàwé sí ìjótìítọ́ Ìjọba náà, tí a ṣàlàyé nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àmọ́ ṣáá o, ìbẹ̀rẹ̀ lásán ni fífi ìwé pẹlẹbẹ sóde fún olùfìfẹ́hàn kan jẹ́. (1 Kọr. 9:23) Ẹ jẹ́ kí a tètè ṣiṣẹ́ lórí gbogbo ìwé tí a fi síta, pẹ̀lú ète fífi ìkẹ́kọ̀ọ́ lọni nínú ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Báwo ni a ṣe lè ṣàṣeparí èyí nínú oṣù August?

2 A lè fi ìwé pẹlẹbẹ náà, “Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!” lọni, pẹ̀lú ìgbékalẹ̀ kúkúrú kan. Bí o ti ń fi àwọn àwòrán ẹ̀yìn rẹ̀ hàn, o lè sọ pé:

◼ “Èmi yóò fẹ́ láti fi ohun kan tí ó ní ìhìn iṣẹ́ alárinrin nínú hàn ọ́.” Ṣí ìwé pẹlẹbẹ náà, Gbádùn Iwalaaye, kí o sì ka ìpínrọ̀ àkọ́kọ́ ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Lẹ́yìn náà, máa bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ pé: “Ó tún dáhùn ìbéèrè yìí [ṣí i sí ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ tí ó wà lókè àwòrán nọmba 8]: ‘Eeṣe ti eniyan fi nkú?’ Ìwọ yóò gbádùn wíwo àwọn àwòrán tí ó wà nínú ìwé pẹlẹbẹ yìí fínnífínní àti kíka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ó wà nínú rẹ̀. Bí o bá fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, o lè ní in fún ọrẹ ₦25.”

3 Kí ni ìwọ yóò sọ nígbà tí o bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò lórí ìwé pẹlẹbẹ náà, “Gbádùn Iwalaaye,” tí o fi síta? O lè gbìyànjú ìyọsíni yìí:

◼ Fi àwòrán nọmba 49 nínú Gbádùn Iwalaaye hàn án, kí o sì béèrè pé, “Àwòrán yìí kò ha jojú ní gbèsè bí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ó ń bẹ nínú ìwé pẹlẹbẹ tí mo fi sílẹ̀ fún ọ nígbà ìbẹ̀wò mi tí ó kẹ́yìn. Èmi yóò fẹ́ láti béèrè ìbéèrè tí ó wà ní ojú ewé tí ó tẹ̀ lé e lọ́wọ́ rẹ.” Ṣí i sí àwòrán nọmba 50, kí o sì ka ìbéèrè náà: “‘Iwọ ha fẹ́ walaaye titilae ninu paradise ẹlẹwà naa bí?’ [Jẹ́ kí ó fèsì.] Tí ó bá jẹ́ ohun tí o fẹ́ nìyẹn, kíyè sí ohun tí ó sọ pé o ní láti ṣe: ‘Nigba naa kẹ́kọ̀ọ́ siwaju si i nipa ohun ti Ọlọrun sọ.’ [Ka Jòhánù 17:3.] Inú mi yóò dùn láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú rẹ lọ́fẹ̀ẹ́. Ìwọ yóò ha fẹ́ bẹ́ẹ̀ bí?” Ṣe àdéhùn tí ó ṣe gúnmọ́ láti padà wá.

4 Nígbà tí o bá ń fi ìwé pẹlẹbẹ náà, “Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun” lọni, o lè bẹ̀rẹ̀ nípa fífi gbogbo àwòrán ẹ̀yin rẹ̀ hàn án, kí o sì béèrè pé:

◼ “Kí ni ìwọ́ rò pé yóò gbà láti sọ gbogbo ilẹ̀ ayé di báyìí?” Jẹ́ kí ó fèsì. Ṣàlàyé díẹ̀ lára àwọn ohun tí ó wà nínú àwòrán náà, tí a sọ ní ojú ìwé 3. Lẹ́yìn náà, sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ènìyàn ronú pé kò ṣeé ṣe láti sọ ayé di báyìí. Ṣùgbọ́n, kì í ṣe ohun tí kò ṣeé ṣe fún Ọlọ́run láti ṣàṣeparí. [Ṣàjọpín kókó tí ó wà ní ìpínrọ̀ 43 pẹ̀lú rẹ̀; lẹ́yìn náà, ka Aísáyà 9:6, 7.] Ọlọ́run ti ṣèlérí láti mú ayé tuntun kan wá, nínú èyí tí àwọn ènìyàn láti inú gbogbo orílẹ̀-èdè yóò ti gbádùn párádísè àgbàyanu kan. Èmi yóò fẹ́ kí o ka ìwé pẹlẹbẹ yìí. Yóò fi hàn ọ́ bí ìwọ àti ìdílé rẹ ṣe lè gbádùn ọjọ́ ọ̀la àgbàyanu kan, tí Ọlọ́run ń mú bọ̀.”

5 Nígbà ìpadàbẹ̀wò, o lè lo ìwé pẹlẹbẹ náà, “Sawo O!” láti ṣàlàyé ìdí tí ó fi ṣe pàtàkì láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì síwájú sí i. Bóyá o lè fi ẹ̀yìn ìwé náà hàn án lẹ́ẹ̀kan sí i, kí o sì sọ pé:

◼ “Nígbà tí mo kọ́kọ́ fi àwòrán yìí hàn ọ́, a gbà pé a óò nífẹ̀ẹ́ láti gbé nínú irú ayé àgbàyanu bí irú èyí. Láti mú kí èyí ṣeé ṣe, ohun kan wà tí gbogbo wá ní láti ṣe.” Ṣí ìwé pẹlẹbẹ náà, “Sawo O!” sí ìpínrọ̀ 52; ka ìpínrọ̀ náà àti ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú Jòhánù 17:3. So ìsọfúnni náà mọ́ àkàwé tí ó wà nínú ìpínrọ̀ 53, nípa ìmọ̀ ẹ̀kọ́ Bíbélì yíyẹ, kí o sì ṣàlàyé pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń pèsè irú ìtọ́ni bẹ́ẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́ nínú ilé àwọn ènìyàn. Fínnúfíndọ̀ yọ̀ǹda láti fi bí a ti ń ṣèkẹ́kọ̀ọ́ hàn án, ní lílo ìwé Ìmọ̀.

6 Nígbà tí o bá ń fi ìwé pẹlẹbẹ náà, “Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá” lọni, o lè gbìyànjú sísọ pé:

◼ “Mo ti gbọ́ tí ọ̀pọ̀ ènìyàn sọ pé, àwọn yóò fẹ́ láti gbé lábẹ́ ìjọba kan tí ó lè yanjú àwọn ìṣòro ńlá tí a dojú kọ lónìí. [Mẹ́nu ba àwọn ìṣòro àdúgbò, bí àìríṣẹ́ṣe, ìwà ọ̀daràn tí ń peléke sí i, tàbí ìjoògùnyó.] Àwọn ohun wọ̀nyí kì í fi ọkàn wa balẹ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la fún àwa fúnra wa àti àwọn àyànfẹ́ wa. Ìwọ ha rò pé ìjọba kan yóò wà tí yóò yanjú àwọn ìṣòro wọ̀nyí bí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ó ṣeé ṣe kí o ti gba Àdúrà Olúwa. Bí o bá ti ṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ ha mọ̀ pé ìwọ ń gbàdúrà ní ti gidi fún ìjọba òdodo kan?” Ṣí ìwé pẹlẹbẹ náà, Akoso, sí ojú ìwé 3, kí o sì ka àwọn ìpínrọ̀ méjì àkọ́kọ́. Fi ìwé pẹlẹbẹ náà lọ̀ ọ́.

7 Bí o bá fi ìwé pẹlẹbẹ náà, “Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá” síta, o lè bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò náà nígbà ìpadàbẹ̀wò nípa sísọ pé:

◼ “Ní ìjelòó, a jíròrò ìjẹ́pàtàkì níní ìjọba òdodo kan tí ó lè yanjú ìṣòro ènìyàn. Ìwé pẹlẹbẹ tí mo fi sílẹ̀ fún ọ tọ́ka sí Ìjọba Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ìrètí kan ṣoṣo tí a ní. Àwọn kan ń ṣe kàyéfì nípa ohun tí ìjọba náà lè ṣe láti mú ìgbésí ayé wa sunwọ̀n sí i. Bíbélì fi hàn pé Kristi ti fi ẹ̀rí hàn pé òun yóò ṣàṣeyọrí níbi tí àwọn aṣáájú ènìyàn ti kùnà.” Ṣí ìwé pẹlẹbẹ náà, Akoso, sí ojú ìwé 29, kí o sì ka àwọn ìpínrọ̀ mẹ́rin tí ó kẹ́yìn. Lẹ́yìn náà, sọ pé: “Ìyẹn kì í ha ń ṣe ọjọ́ ọ̀la àgbàyanu bí? Ìwọ yóò ha fẹ́ láti rí i bí?” Jẹ́ kí ó fèsì. Ka Jòhánù 17:3. Fún un níṣìírí láti kẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ sí i, nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé.

8 Bí o bá ń lo àwọn ìwé pẹlẹbẹ mìíràn, o lè múra ìgbékalẹ̀ tìrẹ sílẹ̀, ní lílo àwọn àbá tí ó wà lókè gẹ́gẹ́ bí àwòkọ́ṣe. Múra sílẹ̀ dáradára, kí o sì wá ìbùkún Jèhófà, bí o ti ń pòkìkí ìhìn rere Ìjọba náà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́