Tọ́jú Rẹ̀
Ǹjẹ́ O Máa Ń Lo Àwọn Ìwé Pẹlẹbẹ Yìí?
Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?
A ṣe é nítorí àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ mọ ohun tó wà nínú Bíbélì, ní pàtàkì àwọn tí kì í ṣe Kristẹni
Bí o ṣe lè fi lọni: “Màá fẹ́ mọ èrò ẹ nípa ohun tí mo fẹ́ kà jáde nínú Ìwé Mímọ́ yìí. [Ka Sáàmù 37:11, èyí tá a tọ́ka sí ní apá 11.] Báwo lo ṣe rò pé ayé máa rí nígbà tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí bá ní ìmúṣẹ? [Jẹ́ kó fèsì.] Èyí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú Bíbélì tó ń fúnni nírètí àti ìtùnú, láìka ibi téèyàn ti wá tàbí ẹ̀sìn téèyàn ń ṣe sí.” Ka ìpínrọ̀ tó wà lókè ní ojú ìwé 3, kó o sì fún un ní ìwé pẹlẹbẹ náà.
O lè lo àbá yìí: Tó o bá ń lo ìwe Bíbélì Fi Kọ́ni láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ẹnì kan tí kì í ṣe Kristẹni, ní gbogbo ìgbà tẹ́ ẹ bá fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́, ẹ lo ìṣẹ́jú mélòó kan láti jíròrò apá kan nínú ìwé pẹlẹbẹ yìí, kí ẹni náà lè mọ ohun tó wà nínú Bíbélì, yálà kẹ́ ẹ tó bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ náà tàbí lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá parí rẹ̀.
Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?
A ṣe é nítorí àwọn tí èèyàn wọn kú
Bí o ṣe lè fi lọni: “Bí ìbátan tàbí ọ̀rẹ́ ẹni bá kú, ó máa ń ṣeni bíi pé kéèyàn mọ ibi tó wà àti bóyá ojú á tiẹ̀ túnra rí lọ́jọ́ kan. Ǹjẹ́ irú ìbéèrè yìí ti wá sí ọ lọ́kàn rí: Kí ní ń ṣẹlẹ̀ sí wa nígbà tí a bá kú?” [Jẹ́ kó fèsì.] Wá ka Jóòbù 14:14, 15 kó o sì máa bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ pé: “Ìwé pẹlẹbẹ yìí sọ ibi tí àwọn èèyàn wa tó ti kú wà àti ìrètí tí wọ́n ní lọ́jọ́ iwájú.”
O lè lo àbá yìí: Ṣí ìwé náà sí ẹ̀kọ́ kìíní kó o sì ka ìpínrọ̀ 4, lẹ́yìn náà kó o wá sọ pé: “Nígbà tí mo bá pa dà wá, a máa jíròrò ìdáhùn tó ń tẹ́ni lọ́rùn tí Bíbélì fúnni lórí ìbéèrè yìí.” Jíròrò àwọn ìpínrọ̀ mélòó kan nínú ẹ̀kọ́ 9 nígbà tó o bá pa dà lọ.
Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!
A ṣe é nítorí àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ kàwé tàbí àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀wé kà
Bí o ṣe lè fi lọni: “Ǹjẹ́ o rò pé ó ṣeé ṣe fún wa láti di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run? [Jẹ́ kó fèsì, kó o wá ka Jákọ́bù 2:23.] A ṣe ìwé pẹlẹbẹ yìí kó lè ràn wá lọ́wọ́ láti di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run bí Ábúráhámù náà ṣe di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run.”
O lè lo àbá yìí: Yálà nígbà àkọ́kọ́ tó o wàásù fún ẹnì kan tàbí nígbà ìpadàbẹ̀wò, jíròrò díẹ̀ tàbí gbogbo àlàyé inú ẹ̀kọ́ 1 pẹ̀lú ẹni náà láti fi bá a ṣe máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì hàn án.
A Satisfying Life—How to Attain It
A ṣe é nítorí àwọn tí kò nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn
Bí o ṣe lè fi lọni: “Ìdí tá a fi wá sọ́dọ̀ rẹ ni pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń fẹ́ kí ayé wọn túbọ̀ ládùn kó lóyin. Gbogbo wa pátá la ní àwọn ìṣòro tó ń kó ẹ̀dùn ọkàn báni. Tí ọ̀ràn bá sì rí bẹ́ẹ̀, a máa ń wá ìmọ̀ràn lọ sọ́dọ̀ ìbátan tàbí ọ̀rẹ́ wa tá a fọkàn tán, a lè lọ ka ìwé tó sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro wa tàbí kí a lọ sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ibo lo rò pé èèyàn ti lè rí ìmọ̀ràn tó wúlò? [Jẹ́ kó fèsì.] Ó ya àwọn kan lẹ́nu pé ìmọ̀ràn tó wúlò wà nínú Bíbélì. Ọ̀kan nínú ìmọ̀ràn náà nìyí. [Fi orí 2 han onílé, kó o wá ka ọ̀kan lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ wà nínú ìwé náà.] A ṣe ìwé pẹlẹbẹ yìí láti ṣàlàyé béèyàn ṣe lè dẹni tí ayé ẹ̀ ládùn tó lóyin.”
O lè lo àbá yìí: Bí onílé bá gba ìwé pẹlẹbẹ náà, sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ló ti gbà pé irọ́ ló kún inú Bíbélì. Nígbà tí mo bá pa dà wá, màá fẹ́ láti fi ohun ìyàlẹ́nu kan hàn ọ́, ìyẹn àpẹẹrẹ bí ọ̀rọ̀ inú Bíbélì ṣe bá ìwádìí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì mu.” Nígbà tó o bá pa dà lọ, ẹ gbé ìpínrọ̀ 4 ní ojú ìwé 12 yẹ̀ wò.
The Origin of Life—Five Questions Worth Asking
A ṣe é nítorí àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni tí wọ́n wà níléèwé, tí wọ́n ń kọ́ ní ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n, ó sì tún wúlò nígbà tá a bá ń jíròrò pẹ̀lú àwọn tí kò gbà pé Ọlọ́run wà àti àwọn tó gbà pé Ọlọ́run kò ṣeé mọ̀ (Ìwé pẹlẹbẹ yìí kò sí lára àwọn ìtẹ̀jáde tá a lè fi lọni lẹ́nu ìwàásù ilé-dé-ilé.)
Bí o ṣe lè lò ó nígbà tó o bá ń bá ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n tàbí ẹni tí kò gbà pé Ọlọ́run wà sọ̀rọ̀: “Èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ìwé sáyẹ́ǹsì lónìí ló fi ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n kọ́ni. Ṣé o gbà pé ìwádìí ṣì ń lọ nípa ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n tàbí o rò pé wọ́n ti wá f ìdí òótọ́ ẹ̀kọ́ náà múlẹ̀ báyìí? [Jẹ́ kó fèsì.] Kéèyàn tó lè sọ pé ohun tí òun gbà gbọ́ dá òun lójú, mo mọ̀ pé ìwọ náà máa gbà pé èèyàn ní láti ṣàyẹ̀wò irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ dáadáa. Ìwé pẹlẹbẹ yìí ní àwọn ẹ̀rí mélòó kan nínú tó mú kí ọ̀pọ̀ gbà gbọ́ pé Ọlọ́run ló dá àwọn nǹkan tó ń bẹ láyé.”
O lè lo àbá yìí: Tó o bá lọ sí iléèwé, fi ìwé pẹlẹbẹ yìí sí orí tábìlì rẹ kó o wá máa wò ó bóyá àwọn ọmọ kíláàsì rẹ á bẹ̀rẹ̀ sí í yẹ̀ ẹ́ wò.
Why Should We Worship God in Love and Truth?
A ṣe é nítorí àwọn ẹlẹ́sìn Híńdù
Bí o ṣe lè fi lọni: “Àdúrà kan tí àwọn ará Íńdíà mọ̀ bí ẹni mọ owó lọ báyìí pé: ‘Gbà mí lọ́wọ́ irọ́, jẹ́ kí n mọ òótọ́. Mú mi jáde kúrò nínú òkùnkùn bọ́ sínú ìmọ́lẹ̀.’ Ǹjẹ́ o rò pé ó ṣe pàtàkì pé kéèyàn jọ́sìn Ọlọ́run ní ìfẹ́ àti ní òtítọ́? [Jẹ́ kó fèsì.] Kíyè sí ohun tí Jésù sọ nípa èyí.” Ka Jòhánù 4:24. Wá ka ìpínrọ̀ 4 ní ojú ìwé 3 kó o sì fún un ní ìwé pẹlẹbẹ náà.
O lè lo àbá yìí: Tí onílé bá gba ìwé pẹlẹbẹ náà, sọ pé: “Àwọn amòye nínú ẹ̀sìn Híńdù sọ pé inú ọkàn àwa èèyàn ni òtítọ́ wà. Àwọn míì sọ pé èèyàn lè rí òtítọ́ nínú Ìwé Mímọ́. Nígbà tí mo bá pa dà wá, màá fẹ́ kí a jíròrò ìbéèrè kan tó wà ní ìparí ìpínrọ̀ 3 ní ojú ìwé 4 tó kà pé: ‘Níbo la ti lè rí òtítọ́ tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run?’”
The Pathway to Peace and Happiness
A ṣe é nítorí àwọn ẹlẹ́sìn Búdà
Bí o ṣe lè fi lọ àgbàlagbà kan tó jẹ́ ẹlẹ́sìn Búdà: “Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bí ominú ṣe ń kọ mí ló ń kọ ẹ̀yin náà lóminú pé àṣàkaṣà ń gbòde kan, àti pé ó ń nípa búburú lórí àwọn ọmọ wa. Kí ni ẹ̀yin rò pé ó fà á tí ìṣekúṣe fi wá dohun tí àwọn ọ̀dọ́ fi ń ṣayọ̀? [Jẹ́ kó fèsì.] Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé nǹkan yìí ti wà ní àkọọ́lẹ̀ nínú ìwé kan tí wọ́n ti kọ lọ́jọ́ pípẹ́ ṣáájú kí ẹ̀sìn Kristẹni, Híńdù àti ti Mùsùlùmí tó bẹ̀rẹ̀? [Ka 2 Tímótì 3:1-3.] Ẹ kíyè sí pé ṣe ni ìwà yìí túbọ̀ ń burú sí i láìka bí àwọn èèyàn ṣe tẹra mọ́ ìwé kíkà sí. [Ka ẹsẹ 7.] Àlàyé tó wà nínú ìtẹ̀jáde yìí ti mú kí n mọ àwọn òtítọ́ kan tí kò hàn sí ọ̀pọ̀ èèyàn. Ṣé ẹ máa fẹ́ láti kà á?”
O lè lo àbá yìí: Lọ́jọ́ tó o bá máa pa dà lọ ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ onílé náà, lẹ́yìn tó o bá ti mú kó nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ inú Bíbélì, fi ìbéèrè tó wà lẹ́yìn ìwé náà hàn án, kó o wá fi ibi tó máa kọ ọ̀rọ̀ sí láti béèrè fún ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni hàn án. Sọ fún un pé ìwé náà wà lọ́wọ́ rẹ tó bá máa fẹ́ láti rí i. Fi ibi tá a to àwọn ẹ̀kọ́ tó wà nínú ìwé náà sí hàn án, kẹ́ ẹ sì jọ jíròrò ìpínrọ̀ kan tàbí méjì nínú àkòrí tó bá wù ú.
Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I?
A ṣe é nítorí àwọn tó ń gbé nílẹ̀ Áfíríkà
Bí o ṣe lè fi lọni: “Ǹjẹ́ o rò pé gbogbo ìsìn ló ń fi òtítọ́ kọ́ni? [Lẹ́yìn tó bá ti dáhùn, máa bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ.] Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dá sílẹ̀ báyìí, àwọn kan sì lè máa ronú pé kò sí èyí tí èèyàn lọ tí kò lè sin Ọlọ́run níbẹ̀. Àmọ́, nínú 1 Tẹsalóníkà 5:21, Ọlọ́run kìlọ̀ fún wa pé kí á ṣọ́ra. [Kà á.] Kí nìdí tí a fi lè sọ pé kì í ṣe ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni gbogbo ìsìn ti wá? Kíyè sí gbólóhùn méjì àkọ́kọ́ tó wà ní ojú ìwé 5, ìpínrọ̀ 3, nínú ẹ̀kọ́ kìíní ìwé pẹlẹbẹ yìí. [Kà á.] Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo ìsìn ló jẹ́ òótọ́, báwo la ṣe lè mọ èyí tó jẹ́ òótọ́? Ìwé pẹlẹbẹ yìí máa jẹ́ kó o mọ̀ ọ́n.”
O lè lo àbá yìí: “Tá a bá fẹ́ kí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa kí ó sì dáàbò bò wá, a gbọ́dọ̀ jọ́sìn rẹ̀ lọ́nà tó tọ́. Nítorí náà, tí mo bá pa dà wá, a jọ máa jíròrò ìbéèrè tó wà ní ojú ìwé 19, “Ǹjẹ́ Gbogbo Ẹ̀sìn ni Ọlọ́run Tẹ́wọ́ Gbà?”
Ẹmi Awo̩n Oku—Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi?
A ṣe é nítorí àwọn tó ń gbé nílẹ̀ Áfíríkà
Bí o ṣe lè fi lọni: “Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló gbà gbọ́ pé àwọn tó ti kú máa ń lọ sí ilẹ̀ àwọn òkú, láti ibi tí wọ́n ti máa ń kíyè sí àwọn tó wà láyé tí wọ́n sì máa ń darí wọn. Ṣé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí?” [Jẹ́ kó fèsì.] Wá ka Oníwàásù 9:5, 10, kó o sì máa bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ pé: “Tó bá jẹ́ pé ohun tí àwọn èèyàn gbà gbọ́ náà kì í ṣe òótọ́, àwọn wo wá ni àwọn tí wọ́n pe ara wọn ní àwọn ẹ̀mí òkú? Ẹ máa rí ìdáhùn ìbéèrè yìí nínú ìwé pẹlẹbẹ yìí.” Fún onílé ní ìwé pẹlẹbẹ náà.
O lè lo àbá yìí: Bí onílé bá gba ìwé pẹlẹbẹ náà, ṣí i sí ojú ìwé 13 kó o wá sọ fún un pé kí ó ka ìpínrọ̀ kìíní. Ṣe àdéhùn ọjọ́ tó o máa pa dà lọ láti máa bá ìjíròrò náà lọ.
Ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run Ló Máa Ṣamọ̀nà Ẹ̀dá Wọ Párádísè
A ṣe é nítorí àwọn Mùsùlùmí tó ń gbé ní àgbègbè tó ti lè rọrùn fún wọn láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Bí o ṣe lè fi lọni: “Mo mọ̀ pé àwọn Mùsùlùmí ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run kan ṣoṣo, wọ́n sì gba gbogbo àwọn wòlíì gbọ́. Ṣé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí? [Jẹ́ kó fèsì.] Màá fẹ́ kí á jọ sọ̀rọ̀ nípa àsọtẹ́lẹ̀ ìgbà láéláé kan tó sọ pé Ọlọ́run máa sọ ayé yìí di Párádísè. Ẹ jẹ́ kí n ka ohun tí wòlí ì kan kọ sílẹ̀. [Ka Aísáyà 11:6-9.] Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ṣe kàyéfì pé báwo gan-an ni Ọlọ́run ṣe máa ṣe ìyípadà yìí. Ìwé pẹlẹbẹ yìí jẹ́ ká mọ ohun tí àwọn wòlíì sọ nípa ọ̀rọ̀ yìí.”
O lè lo àbá yìí: Tí onílé bá gba ìwé pẹlẹbẹ náà, kí o sọ pé: “Ìwé Ọlọ́run yìí ṣàlàyé pé, ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ inú Párádísè ni èèyàn ń gbé. Nígbà mí ì tá a bá máa jọ jíròrò, màá fẹ́ láti dáhùn ìbéèrè yìí, ‘Kí ló fà á tí ẹ̀dá èèyàn fi kọ ẹ̀yìn sí ìtọ́ni Ọlọ́run tí wọ́n sì pàdánù Párádísè?’” Nígbà tó o bá pa dà lọ, jíròrò apá tó bẹ̀rẹ̀ ní ojú ìwé 6.
Ìgbàgbọ́ Òdodo Ló Máa Mú Kó O Ní Ayọ̀
A ṣe é nítorí àwọn Mùsùlùmí tó ń gbé ní àgbègbè tó ti lè rọrùn fún wọn láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
Bí o ṣe lè fi lọni: Fi àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16 àti 17 hàn án, kí o wá sọ pé: “Ohun tó wà nínú àwòrán yìí yàtọ̀ pátápátá sí ohun tí à ń rí láyé lónìí. Ǹjẹ́ o rò pé ọjọ́ kan ń bọ̀ tí ayé yìí máa rí bí èyí tó wà nínú àwòrán yìí? [Jẹ́ kó fèsì.] Wo ohun tí ìwé Ọlọ́run yìí ṣèlérí. [Ka ọ̀kan lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nínú ìwé pẹlẹbẹ náà jáde látinú Bíbélì rẹ.] Ìwé pẹlẹbẹ yìí máa ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o lè ní ìgbàgbọ́ tó dájú pé àwọn ìlérí Ọlọ́run máa ní ìmúṣẹ.”
O lè lo àbá yìí: Kó o tó kúrò lọ́dọ̀ ẹni tó o wàásù fún nígbà àkọ́kọ́, ní kó mú ọ̀kan nínú àwọn ìbéèrè tó wà lẹ́yìn ìwé pẹlẹbẹ náà. Wá ṣe àdéhùn ìgbà tó o máa pa dà lọ láti dáhùn ìbéèrè náà.
Lasting Peace and Happiness—How to Find Them
A ṣe é nítorí àwọn ará Ṣáínà
Bí o ṣe lè fi lọni: “Ọ̀pọ̀ ìṣòro tó ń kó ẹ̀dùn ọkàn báni ló kún inú ayé lónìí. Kí ló ń mú kó o láyọ̀ láìka àwọn ìṣòro tó wà láyé yìí sí? [Jẹ́ kó fèsì.] Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń láyọ̀ bí wọ́n ṣe ń fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò. [Ka Sáàmù 119:1, 2.] Àwọn kan sọ pé ìwé àwọn òyìnbó ni Bíbélì. Àmọ́, kíyè sí gbólóhùn yìí. [Ka ìpínrọ̀ 16 ní ojú ìwé 17.] Ìwé pẹlẹbẹ yìí sọ bá a ṣe lè ní àlàáfíà àti ayọ̀ tí kò lópin.”
O lè lo àbá yìí: Tí onílé bá gba ìwé pẹlẹbẹ náà, ẹ jọ ka àwọn gbólóhùn mẹ́ta àkọ́kọ́ tó wà ní ìpínrọ̀ 18 ní ojú ìwé 17 kó o wá sọ pé: “Nígbà tí mo bá pa dà wá, màá fi ohun kan tí Bíbélì ní ká máa retí lọ́jọ́ iwájú hàn ọ́.” Nígbà tó o bá pa dà lọ, jíròrò ọ̀kan lára àwọn kókó tó wà ní ìpínrọ̀ 6 ní ojú ìwé 30.