Ẹ̀kọ́ 1
Ọlọ́run Ń pè ọ́ Pé Kí o Wá Di Ọ̀rẹ́ Òun
Ọlọ́run ń fẹ́ kí o jẹ́ ọ̀rẹ́ òun. Ǹjẹ́ o tíì ronú rẹ̀ rí pé o lè di ọ̀rẹ́ Ẹni títóbilọ́lá jù lọ ní àgbáálá ayé? A pe Ábúráhámù, tó gbé ayé lọ́pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn, ní ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. (Jákọ́bù 2:23) Àwọn mìíràn tún wà tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn pé wọ́n bá Ọlọ́run dọ́rẹ̀ẹ́ tí Ọlọ́run sì bù kún wọn gidigidi. Lónìí, àwọn èèyàn láti apá ibi gbogbo lórí ilẹ̀ ayé ti di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Ìwọ́ pẹ̀lú lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run.
Jíjẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run dára ju jíjẹ́ ọ̀rẹ́ èèyàn èyíkéyìí lọ. Ọlọ́run kì í dójú ti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí wọ́n dúró ṣinṣin. (Sáàmù 18:25) Kéèyàn jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run dára ju kéèyàn jẹ́ olówó lọ. Nígbà tẹ́nì kan tó jólówó bá kú, ńṣe ni owó rẹ̀ máa ń di tàwọn ẹlòmíràn. Ṣùgbọ́n, kò sẹ́ni tó lè gba ìṣura tí ẹni tó bá Ọlọ́run dọ́rẹ̀ẹ́ tò jọ.—Mátíù 6:19.
Àwọn èèyàn kan lè gbìyànjú láti ṣí ọ lọ́wọ́ kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run. Kódà, díẹ̀ lára àwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn aráalé rẹ lè ṣe èyí. (Mátíù 10:36, 37) Bí àwọn ẹlòmíràn bá ń fi ọ́ rẹ́rìn-ín tàbí tí wọ́n ń halẹ̀ mọ́ ọ, bi ara rẹ léèrè pé, ‘Ta ni mo fẹ́ tẹ́ lọ́rùn, ṣé èèyàn ni tàbí Ọlọ́run?’ Ronú nípa èyí ná: Bí ẹnì kan bá sọ pé o ò gbọ́dọ̀ jẹun mọ́ rárá, ṣé wàá gbà fún un? Ó dájú pé o ò ní gbà! Oúnjẹ ló ń gbẹ́mìí èèyàn ró. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ló lè mú kóo wà láàyè títí láé! Nítorí náà, má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣí ọ lọ́wọ́ kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa bóo ṣe lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run.—Jòhánù 17:3.