Wàásù fún “Ènìyàn Gbogbo”
1. Báwo ni àwọn oníwàásù ìhìn rere tó dáńgájíá ṣe dà bí ọ̀jáfáfá oníṣẹ́ ọnà?
1 Ọ̀jáfáfá oníṣẹ́ ọnà máa ń ní ọ̀pọ̀ irin iṣẹ́, ó sì máa ń mọ ìgbà tó yẹ kó lò wọ́n àti ọ̀nà tó yẹ kó gbà lò wọ́n. Bákan náà, a ní oríṣiríṣi irin iṣẹ́ tó lè ràn wá lọ́wọ́ kí a lè ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ wa gẹ́gẹ́ bí ajíhìnrere. Bí àpẹẹrẹ, a ti ṣe àwọn ìwé pẹlẹbẹ tó sọ̀rọ̀ lórí oríṣiríṣi nǹkan, èyí tó ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè wàásù fún “ènìyàn gbogbo.” (1 Kọ́r. 9:22) A to orúkọ àwọn ìwé pẹlẹbẹ kan sínú àfikún tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí, a sọ àwọn tá a torí wọn ṣe é àti àwọn àbá nípa bá a ṣe lè lo àwọn ìwé pẹlẹbẹ náà lóde ẹ̀rí.
2. Àwọn ìgbà wo la lè lo ìwé pẹlẹbẹ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?
2 Àwọn Ìgbà Tá A Lè Lo Ìwé Pẹlẹbẹ: Ọ̀jáfáfá oníṣẹ́ ọnà máa ń lo irin iṣẹ́ kan nígbàkigbà tí irin iṣẹ́ náà bá máa ṣàǹfààní. Bákan náà, a lè lo ìwé pẹlẹbẹ nígbàkigbà tá a bá rí i pé ó máa ṣe ẹnì kan láǹfààní, kì í wulẹ̀ ṣe ní àwọn oṣù tá a bá sọ pé ìwé pẹlẹbẹ ni kí á lò lóde ẹ̀rí. Bí àpẹẹrẹ, tó bá jẹ́ pé ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni là ń lò ní oṣù kan, tó sì jẹ́ pé àwọn tí kì í ṣe Kristẹni ló wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù tá a ti fẹ́ ṣiṣẹ́, tí wọn kò sì fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ Bíbélì, ó lè ṣàǹfààní tá a bá lo ìwé pẹlẹbẹ kan tó ṣeé ṣe kí ẹni tá à ń wàásù fún nífẹ̀ẹ́ sí, kí a ṣẹ̀ṣẹ̀ wá fi ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni hàn án, lẹ́yìn tá a ti sọ̀rọ̀ lọ́nà tó máa mú kí ó nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́.
3. Kí nìdí tó fi yẹ kí a jẹ́ ọ̀jáfáfá nínú lílo àwọn irin iṣẹ́ tá a fi ń wàásù?
3 Bíbélì gbóríyìn fún àwọn tó bá jẹ́ ọ̀jáfáfá lẹ́nu iṣẹ́ wọn. (Òwe 22:29) Ó dájú pé, kò sí iṣẹ́ mìíràn tó ṣe pàtàkì ju “iṣẹ́ mímọ́ ti ìhìn rere.” (Róòmù. 15:16) Tá a bá fẹ́ jẹ́ “aṣiṣẹ́ tí kò ní ohun kankan láti tì í lójú,” àfi ká máa sapá gidigidi ká lè túbọ̀ di ọ̀jáfáfá nínú lílo àwọn irin iṣẹ́ wa.—2 Tím. 2:15.