Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Tẹ́tí sí Ọlọ́run
1. Àwọn ìwé pẹlẹbẹ wo la mú jáde ní Àpéjọ Àgbègbè “Kí Ìjọba Ọlọ́run Dé!” kí ló sì mú kí wọ́n jẹ́ irinṣẹ́ tó wúlò gan-an?
1 Ìwé pẹlẹbẹ tuntun méjì náà Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé àti ẹ̀dà rẹ̀ tí ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ kò pọ̀ rárá, Tẹ́tí sí Ọlọ́run la mú jáde ní Àpéjọ Àgbègbè “Kí Ìjọba Ọlọ́run Dé!” Torí pé àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú àwọn ìwé náà kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀, ó rọrùn láti túmọ̀, iṣẹ́ ìtúmọ̀ náà kò sì gba àkókò tó pọ̀. Kódà, gbàrà tá a ti mú ìwé Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé jáde ni ètò Ọlọ́run ti fọwọ́ sí i pé ká túmọ̀ rẹ̀ sí irínwó àti mọ́kàn-lé-lọ́gbọ̀n [431] èdè.
2. Àwọn wo ló máa jàǹfààní àwọn ìwé pẹlẹbẹ yìí?
2 Àwọn wo gan-an ló máa jàǹfààní àwọn ìwé pẹlẹbẹ yìí? Ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ yíká ayé, irú bí àwọn tá a mẹ́nu kàn nísàlẹ̀ yìí:
• Akéde kan ń jíròrò ohun kan pẹ̀lú onílé fún ìgbà àkọ́kọ́ tàbí nígbà ìpadàbẹ̀wò, àmọ́ ó kíyè sí i pé onílé náà kò lè kàwé rárá tàbí kò mọ ìwé kà dáadáa.
• Akéde kan ń wàásù fún àwọn èèyàn kan, àmọ́ kò fi bẹ́ẹ̀ sí àwọn ìtẹ̀jáde wa ní èdè tí wọ́n ń sọ tàbí kò sí ìtẹ̀jáde wa kankan lédè náà. Ó sì lè jẹ́ pé èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù náà ni kò lè kàwé ní èdè tí wọ́n ń sọ.
• Akéde kan ń fi èdè àwọn adití wàásù fún àwọn adití ní ìpínlẹ̀ ìwàásù rẹ̀.
• Òbí kan tàbí akéde kan ń fẹ́ láti fi òtítọ́ kọ́ ọmọ rẹ̀ kékeré tí kò tíì mọ̀wé kà.
3. Kí làwọn ohun tó wà nínú ìwé pẹlẹbẹ Tẹ́tí sí Ọlọ́run?
3 Ohun Tó Wà Nínú Àwọn Ìwé Náà: Àwọn ọ̀rọ̀ inú ìwé Tẹ́tí sí Ọlọ́run kò pọ̀ rárá, ohun tó wà lójú ìwé kọ̀ọ̀kan kò ju gbólóhùn ọ̀rọ̀ kan lọ àti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a kọ sísàlẹ̀ ojú ìwé náà. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Ká sọ pé ẹnì kan fún ẹ ní ìwé pẹlẹbẹ kan tí wọ́n kọ ní èdè tí o kò lè kà, tí gbogbo ohun tí wọ́n kọ sínú ìwé náà sì ṣàjèjì lójú rẹ. Ǹjẹ́ ìwé náà máa wù ọ́, kódà bí wọ́n bá tiẹ̀ ya àwọn àwòrán mèremère sínú rẹ̀? Kò dájú pé ó máa wù ẹ́. Bákan náà, àwọn ìwé tí ọ̀rọ̀ bá pọ̀ nínú rẹ̀ sábà máa ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn tí kò lè kàwé. Torí náà, àwọn àwòrán tá a fara balẹ̀ yà wà ní ojú ìwé kọ̀ọ̀kan, àwọn àwòrán náà sì ní àmì tó ń tọ́ka sí àwòrán tó kàn tí ẹ máa jíròrò.
4. Kí làwọn ohun tó wà nínú ìwé pẹlẹbẹ Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé?
4 Àwọn àwòrán kan náà ló wà nínú ìwé Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé àti Tẹ́tí sí Ọlọ́run. A ṣe é láti fi kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú àwọn tí kò mọ̀wé kà tàbí àwọn tó ṣì ń kọ́ bí wọ́n ṣe lè kàwé. A lè lo ìwé Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé láti fi kọ́ onílé lẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé Tẹ́tí sí Ọlọ́run. Ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan nínú ìwé náà gba ojú ìwé méjì-méjì, ìbéèrè tá a dáhùn nínú ẹ̀kọ́ náà sì máa ń wà ní ọwọ́ òkè lápá òsì. A fi àlàyé díẹ̀ àtàwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí kún àwọn àwòrán inú ìwé náà. Ní apá ìsàlẹ̀ èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ojú ìwé náà, àpótí kan wà tí àwọ̀ rẹ̀ yàtọ̀, tó ní àwọn àfikún àlàyé àtàwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a lè lò láti fi bá akẹ́kọ̀ọ́ jíròrò bí òye rẹ̀ bá ṣe mọ.
5. Ìgbà wo la lè lo àwọn ìwé pẹlẹbẹ yìí, báwo la sì ṣe lè lò wọ́n lóde ẹ̀rí?
5 Bá A Ṣe Lè Lo Àwọn Ìwé Náà: O lè lo èyíkéyìí nínú àwọn ìwé pẹlẹbẹ méjèèjì yìí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé nígbàkigbà tó o bá rí i pé ó yẹ bẹ́ẹ̀, kódà tí kì í bá ṣe ìwé pẹlẹbẹ là ń lò lóde ẹ̀rí lóṣù náà. (Wo àpótí tá a pe àkọlé rẹ̀ ní “Bá A Ṣe Lè Fi Àwọn Ìwé Náà Lọni.”) O tún lè lò ó nígbà ìpadàbẹ̀wò, o kàn lè sọ fún onílé tó fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ wa pé o fẹ́ fi nǹkan kan hàn án, kó o wá fún un ní ọ̀kan lára àwọn ìwé pẹlẹbẹ náà.
6. Báwo la ṣe lè fi àwọn ìwé pẹlẹbẹ yìí kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
6 Torí pé a kò tẹ ìbéèrè sínú ìwé Tẹ́tí sí Ọlọ́run, a kò ní máa fi ṣe ìjíròrò oníbèéèrè àti ìdáhùn bá a ṣe máa ń ṣe tá a bá ń fi ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni darí ìkẹ́kọ̀ọ́. Kò sẹ́ni tí kì í fẹ́ láti gbọ́ ìtàn. Nítorí náà, máa lo àwọn àwòrán náà láti fi sọ àwọn ìtàn onímìísí tó wà nínú Bíbélì. Ṣàlàyé ohun tí àwọn àwòrán náà túmọ̀ sí. Fi ìtara sọ ọ́. Ní kí akẹ́kọ̀ọ́ náà sọ ohun tó rí àti ohun tó rò nípa àwọn àwòrán náà fún ọ. Ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nísàlẹ̀ àwọn ojú ìwé náà, kó o sì bá onílé fèròwérò lórí ohun tí àwọn ẹsẹ yẹn túmọ̀ sí. Béèrè àwọn ìbéèrè tó máa jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ lóhùn sí ìjíròrò náà, tó sì máa jẹ́ kó o mọ̀ pé ohun tó ń kọ́ yé e. Tó bá jẹ́ pé ìwé Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé ni akẹ́kọ̀ọ́ náà ń lò, ẹ jọ ka àwọn ọ̀rọ̀ àtàwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà níbi àwòrán kọ̀ọ̀kan, nígbà tẹ́ ẹ bá ń jíròrò àwòrán náà.
7. Báwo la ṣe lè ran akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa lọ́wọ́ kó lè tẹ̀ síwájú?
7 Ran Akẹ́kọ̀ọ́ Lọ́wọ́ Kó Lè Tẹ̀ Síwájú: A nírètí pé ìjíròrò tó o bá ní pẹ̀lú ẹni tí ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa jẹ́ kó wù ú láti mọ ìwé kà kí òun fúnra rẹ̀ bàa lè gba ìmọ̀ Jèhófà sínú. (Mát. 5:3; Jòh. 17:3) Bí ẹ bá ṣe ń bá ìjíròrò yín lọ nínú ìwé Tẹ́tí sí Ọlọ́run, o lè máa kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ náà ní ìwé kíkà, tó o bá ti rí i pé òun fúnra rẹ̀ ti múra tán láti máa kàwé, o lè wá máa lo ìwé Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé láti máa fi kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́. Kódà lẹ́yìn tí akẹ́kọ̀ọ́ náà bá parí ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ nínu ìwé pẹlẹbẹ méjèèjì, kò tíì ní lè ṣèrìbọmi. Ṣe ni kó o wá bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́, tàbí kó o lo ìtẹ̀jáde míì tó máa jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ yẹn túbọ̀ ní òye tó kún nípa Bíbélì.
8. Kí nìdí tá a fi ń dúpẹ́ pé a ní àwọn irinṣẹ́ tuntun tí a óò máa lò lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́?
8 Àwọn èèyàn gbọ́dọ̀ tẹ́tí sí Ọba Aláṣẹ ayé òun ọ̀run tí wọ́n bá máa wà láàyè títí láé. (Aísá. 55:3) Ìfẹ́ Jèhófà ni pé kí “gbogbo onírúurú ènìyàn,” títí kan àwọn tí kò lè kàwé, kọ́ láti máa tẹ́tí sí òun. (1 Tím. 2:3, 4) A mà dúpẹ́ o, pé a ní àwọn irinṣẹ́ tuntun tá a lè máa lò láti kọ́ àwọn èèyàn bí wọ́n ṣe lè tẹ́tí sí Ọlọ́run!
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 3]
Bá A Ṣe Lè Fi Àwọn Ìwé Náà Lọni
Fi ojú ìwé 2 àti 3 han onílé, kó o wá bí i pé: “Ṣé wàá fẹ́ gbé nínú ayé kan tó rí báyìí? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé Mímọ́ ṣèlérí pé Ọlọ́run máa tó sọ ayé yìí di ibi tó lẹ́wà, tí àlááfíà máa wà, tí ẹnikẹ́ni kò ní tòṣì, tí kò sì ní sí ẹni tí yóò máa ṣàìsàn mọ́. Gbọ́ ohun tí a gbọ́dọ̀ ṣe ká lè gbé níbẹ̀. [Ka Aísáyà 55:3, tí a tọ́ka sí lápá òkè ojú ìwé 3.] Ẹsẹ Bíbélì yìí sọ pé ká ‘wá sọ́dọ̀’ Ọlọ́run, ká sì ‘fetí sílẹ̀’ sí i. Ṣùgbọ́n báwo la ṣe lè tẹ́tí sí Ọlọ́run?” Ṣí ìwé náà sí ojú ìwé 4 àti 5 kó o sì jíròrò ìdáhùn ìbéèrè náà pẹ̀lú rẹ̀. Bí onílé ò bá ráyè, fún un ní ìwé pẹlẹbẹ náà, kó o sì ṣètò láti pa dà lọ jíròrò ìdáhùn ìbéèrè náà pẹ̀lú rẹ̀.