Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 16
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JULY 16
Orin 101 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 23 ìpínrọ̀ 16 sí 19, àti àpótí tó wà ní ojú ìwé 188 (25 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Ìsíkíẹ́lì 15-17 (10 min.)
No. 1: Ìsíkíẹ́lì 16:14-27 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Òtítọ́ Wo Ni Jésù Sọ̀rọ̀ Nípa Rẹ̀ Nínú Jòhánù 18:37? (5 min.)
No. 3: Bíbélì Fi Hàn Pé Màríà Kì Í Ṣe “Wúńdíá Títí Lọ”—td 23B (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn Ìfilọ̀.
10 min: Jẹ́ Kí Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́ Kó O Lè Máa Tẹ̀ Síwájú Gẹ́gẹ́ Bí Òjíṣẹ́. Alábòójútó Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ni kó sọ àsọyé yìí tá a gbé ka ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 6, ìpínrọ̀ 1 sí ìparí ojú ìwé 8. Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu akéde kan tàbí méjì nípa bí ilé ẹ̀kọ́ náà ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́.
20 min: “Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Tẹ́tí sí Ọlọ́run.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Nígbà tẹ́ ẹ bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 5, ṣe àṣefihàn kan nípa bí a ṣe lè fún àwọn èèyàn ní ọ̀kan nínú àwọn ìwé pẹlẹbẹ náà. Lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá tí jíròrò ìpínrọ̀ 6, ṣe àṣefihàn oníṣẹ̀ẹ́jú-mẹ́ta kan tó ń fi bí akéde náà ṣe ń fi ìwé pẹlẹbẹ Tẹ́tí sí Ọlọ́run kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tó sì ń jíròrò àwòrán àkọ́kọ́ ní ojú ìwé 4.
Orin 120 àti Àdúrà