ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb17 March ojú ìwé 5
  • Bá A Ṣe Máa Lo Ìwé Tẹ́tí sí Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bá A Ṣe Máa Lo Ìwé Tẹ́tí sí Ọlọ́run
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2017)
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Tẹ́tí sí Ọlọ́run
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
  • Bá A Ṣe Lè Lo Ìwé Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
  • Irin Iṣẹ́ Tuntun Láti Ran Àwọn Ènìyàn Lọ́wọ́ Láti Mọ Àwọn Ohun Tí Ọlọ́run Ń béèrè
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Máa Lo Ìwé “Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!” Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2017)
mwb17 March ojú ìwé 5

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Bá A Ṣe Máa Lo Ìwé Tẹ́tí sí Ọlọ́run

Tẹ́tí sí Ọlọ́run

A ṣe ìwé Tẹ́tí sí Ọlọ́run ká lè máa fi kọ́ àwọn èèyàn ní kókó ẹ̀kọ́ Bíbélì. Ó sì ní onírúurú àwòrán nínú fún àǹfààní àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀wé kà. Ojú ìwé méjì ni ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan ní, a sì fara balẹ̀ ya àwọn àwòrán sí i. Àwòrán kọ̀ọ̀kan ní àmí tó máa darí ìjíròrò látorí àwòrán kan sí òmíràn ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé.

Ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé pẹlẹbẹ Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé pọ̀ ju tinú ìwé Tẹ́tí sí Ọlọ́run lọ, àmọ́ àwòrán kan náà ló wà nínú ìwé méjèèjì. A lè fi ìwé yìí kọ́ ẹni tó mọ̀wé kà díẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́. Àwọn akéde máa ń lo ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ láti fi ṣàlàyé àwọn àwòrán tó wà nínú ìwé Tẹ́tí sí Ọlọ́run. Àwọn ojú ìwé kan máa ń ní àpótí tí àfikún àlàyé wà nínú rẹ̀, ẹ lè lo àpótí yìí bí òye àkẹ́kọ̀ọ́ bá ṣe lè gbé e tó.

Arábìnrin kan ń lo ìwé Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé ẹni tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ sì ń lo ìwé Tẹ́tí sí Ọlọ́run

A lè fi ìwé méjèèjì lọni lóde ẹ̀rí nígbàkigbà, kódà tí kì í bá ṣe òun là ń lò lóṣù náà. Tó o bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, lo àwọn àwòrán inú ìwé náà láti ṣàlàyé àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì. Bi akẹ́kọ̀ọ́ ní ìbéèrè, kó o sì rí i pé ẹ̀kọ́ náà yé e dáadáa. Ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí nísàlẹ̀ ojú ìwé kọ̀ọ̀kan, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀. Tẹ́ ẹ bá ti parí ìwé náà, ẹ kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? kó o lè ran akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́wọ́ kó lè tẹ̀ síwájú débi táá fi ṣèrìbọmi.

Ẹ̀kọ́ nípa Ádámù àti Éfà nígbà tí wọ́n wà ní ọgbà Édẹ́nì látinú ìwé Tẹ́tí sí Ọlọ́run
    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́