March 27–April 2
JEREMÁYÀ 12-16
Orin 135 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Pa Jèhófà Tì”: (10 min.)
Jer 13:1-5—Jeremáyà tẹ̀lé ìtọ́ni tí Jèhófà fún un pé kó tọ́jú ìgbànú aṣọ ọ̀gbọ̀ kan pa mọ́, àmọ́ iṣẹ́ yìí gba ìsapá gan-an (jr 51 ¶17)
Jer 13:6, 7—Nígbà tí Jeremáyà rìnrìn-àjò ọ̀nà jíjìn pa dà láti lọ mú ìgbànú náà, ó rí i pé ó ti bà jẹ́ (jr 52 ¶18)
Jer 13:8-11—Jèhófà fi èyí ṣàpẹẹrẹ pé àjọṣe tímọ́tímọ́ tó wà láàárín òun àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa bà jẹ́ torí pé wọ́n ya alágídí (jr 52 ¶19-20; it-1-E 1121 ¶2)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Jer 12:1, 2, 14—Ìbéèrè wo ni Jeremáyà béèrè, ìdáhùn wo sì ni Jèhófà fún un? (jr 118 ¶11)
Jer 15:17—Kí ni ojú ìwòye Jeremáyà nípa yíyan ọ̀rẹ́, báwo la sì ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀? (w04 5/1 12 ¶16)
Ẹ̀kọ́ wo ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ mi nípa Jèhófà?
Àwọn kókó wo látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí ni mo lè lò lóde ẹ̀rí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Jer 13:15-27
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ìwé ìkésíni síbi Ìrántí Ikú Kristi àti fídíò—Jẹ́ kí onílé mọ̀ pé o máa pa dà wá.
Ìpadàbẹ̀wò: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ìwé ìkésíni síbi Ìrántí Ikú Kristi àti fídíò—Jẹ́ kí onílé mọ̀ pé o máa pa dà wá.
Àsọyé: (6 min.) w16.03 29-31—Àkòrí: Ìgbà Wo Ni Bábílónì Ńlá Mú Àwọn Èèyàn Ọlọ́run Nígbèkùn?
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Ran Ìdílé Rẹ Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Máa Rántí Jèhófà”: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará kọ́kọ́ wo fídíò náà ‘Kí Ọ̀rọ̀ Wọ̀nyí Wà ní Ọkàn Rẹ’—Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) kr orí 10 ¶8-11 àti àpótí ““Ibi Tí Kérésìmesì Ti Ṣẹ̀ Wá Àti Ìdí Tí Wọ́n Fi Ń Ṣe É”” àti “Àwọn Ayẹyẹ Mìíràn Tí Kò Bá Ìwé Mímọ́ Mu”
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 48 àti Àdúrà