ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb17 March ojú ìwé 7
  • Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Pa Jèhófà Tì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Pa Jèhófà Tì
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2017)
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣọ́ra Fún Ọkàn Tó Ń Ṣàdàkàdekè
    Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà
  • “Mo Ti Fi Ọ̀rọ̀ Mi sí Ẹnu Rẹ”
    Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà
  • “Èmi Kò Lè Dákẹ́”
    Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà
  • Jèhófà Rán Jeremáyà Pé Kó Lọ Wàásù
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2017)
mwb17 March ojú ìwé 7

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JEREMÁYÀ 12-16

Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Pa Jèhófà Tì

Jèhófà gbé iṣẹ́ ńlá kan fún Jeremáyà tó máa ṣàpẹẹrẹ ìpinnu tí Jèhófà ṣe láti pa Júdà àti Jerúsálẹ́mù run, torí wọ́n jẹ́ alágídí àti onígbèéraga.

Jeremáyà rìrìn àjò lọ bọ̀ láti Jerúsálẹ́mù sí Odò Yúfírétì

Jeremáyà wá ìgbànú aṣọ ọ̀gbọ

13:1, 2

  • Ìgbànú tí Jeremáyà so mọ́ ìgbáròkó rẹ̀ ṣàpẹẹrẹ àjọṣe tímọ́tímọ́ tíì bá wà láàárín Jèhófà àti orílẹ̀-èdè náà

Jeremáyà mú ìgbànú náà lọ sí Odò Yúfírétì

13:3-5

  • Ó fi í pamọ́ sínú pàlàpálá àpáta gàǹgà, ó sì pa dà sí Jerúsálẹ́mù

Jeremáyà pa dà sí Odò Yúfírétì láti mú ìgbànú náà

13:6, 7

  • Ìgbànú náà ti bà jẹ́

Jèhófà wá ṣàlàyé fún Jeremáyà ohun tí èyí túmọ̀ sí lẹ́yìn tó ti ṣe ohun tó rán-an

13:8-11

  • Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún Jeremáyà dá bí ohun tí kò tó nǹkan, síbẹ̀ ìgbọ̀ràn rẹ̀ jẹ́ ọkàn lára ọ̀nà tí Jèhófà gbà mú kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ wọ àwọn èèyàn náà lọ́kàn

ǸJẸ́ O MỌ̀?

Ìrìn àjò láti Jerúsálẹ́mù sí Odò Yúfírétì jẹ́ nǹkan bíi 500 kìlómítà [300 miles]. Tá a bá ṣírò ìgbà méjèèjì tí Jeremáyà lọ bọ̀, ó jẹ́ nǹkan bíi 2,000 kìlómítà [1,200 miles], tó sì lè gba ọ̀pọ̀ oṣù láti rin ìrìn àjò náà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́