Ẹ̀KỌ́ 57
Jèhófà Rán Jeremáyà Pé Kó Lọ Wàásù
Jèhófà yan Jeremáyà láti jẹ́ wòlíì fáwọn ará ìlú Júdà. Ó ní kó lọ kìlọ̀ fáwọn èèyàn náà pé kí wọ́n jáwọ́ nínú ìwà ibi wọn. Jeremáyà sọ pé: ‘Jèhófà, ọmọ kékeré ni mí. Mi ò mọ bí màá ṣe bá àwọn èèyàn náà sọ̀rọ̀.’ Jèhófà wá sọ fún un pé: ‘Má bẹ̀rù. Màá kọ́ ẹ lóhun tí wàá sọ. Màá sì ràn ẹ́ lọ́wọ́.’
Jèhófà ní kí Jeremáyà pe àwọn àgbààgbà ìlú náà jọ, kó sì fọ́ ìkòkò mọ́lẹ̀ níwájú wọn, kó wá sọ pé: ‘Bí Jerúsálẹ́mù ṣe máa fọ́ sí wẹ́wẹ́ nìyẹn.’ Àwọn àgbààgbà yìí bínú gan-an nígbà tí Jeremáyà ṣe ohun tí Jèhófà rán an. Àlùfáà kan tó ń jẹ́ Páṣúrì lu Jeremáyà, ó sì de ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ̀ sínú àhámọ́. Ní gbogbo òru yẹn, Jeremáyà ò lè mira. Nígbà tí Páṣúrì tú u sílẹ̀ láàárọ̀ ọjọ́ kejì, Jeremáyà sọ pé: ‘Ó tó gẹ́ẹ́, mi ò ṣe mọ́! Mi ò wàásù mọ́.’ Àmọ́, ṣé ó jáwọ́ lóòótọ́? Rárá o. Torí pé nígbà tí Jeremáyà rò ó dáadáa, ó sọ pé: ‘Ńṣe ni ọ̀rọ̀ Jèhófà dà bí iná nínú ara mi. Mi ò lè jáwọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù.’ Jeremáyà sì ń bá a lọ láti máa kìlọ̀ fáwọn èèyàn náà.
Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún, ọba tuntun jẹ ní Júdà. Àwọn àlùfáà àtàwọn wòlíì èké kórìíra Jeremáyà gan-an. Wọ́n sọ fáwọn ọmọ aládé pé: ‘Ẹ jẹ́ ká pa ọkùnrin yìí.’ Jeremáyà sọ pé: ‘Ẹ kàn fẹ́ pa ẹni tí kò ṣẹ̀ ni, torí pé iṣẹ́ tí Jèhófà rán mi ni mò ń jẹ́, kì í ṣe ọ̀rọ̀ ara mi.’ Nígbà táwọn ìjòyè náà gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n sọ pé: ‘Ẹ má ṣe jẹ́ ká pa ọkùnrin yìí.’
Amọ́ inú ń bí àwọn ìjòyè yẹn torí pé Jeremáyà ò yéé wàásù. Ni wọ́n bá tún sọ fún ọba pé kó pa Jeremáyà. Ọba sọ fún wọn pé kí wọ́n ṣe ohun tí wọ́n bá fẹ́. Ni wọ́n bá mú Jeremáyà, wọ́n sì jù ú sínú kòtò kan tí ẹrẹ̀ wà nínú ẹ̀, wọ́n rò pé ibẹ̀ ló máa kú sí. Bí Jeremáyà ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í rì sínú ẹrẹ̀ nìyẹn.
Ọkùnrin kan tó ń ṣiṣẹ́ ní ààfin tórúkọ ẹ̀ ń jẹ́ Ebedi-mélékì sọ fún ọba pé: ‘Àwọn ìjòyè ti ju Jeremáyà sínú kòtò! Tá a bá fi sílẹ̀ níbẹ̀, ó máa kú.’ Ọba wá pàṣẹ pé kí Ebedi-mélékì mú àwọn ọkùnrin ọgbọ̀n (30) pẹ̀lú rẹ̀, kí wọ́n sì lọ yọ Jeremáyà kúrò nínú kòtò náà. Ṣé kò yẹ káwa náà ṣe bíi Jeremáyà, tí kò jẹ́ kí ohunkóhun mú kóun jáwọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù?
“Gbogbo èèyàn sì máa kórìíra yín nítorí orúkọ mi, ṣùgbọ́n ẹni tó bá fara dà á dé òpin máa rí ìgbàlà.”—Mátíù 10:22